Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 69:1-36

Sí olùdarí lórí Òdòdó Lílì.+ Ti Dáfídì. 69  Gbà mí là, Ọlọ́run, nítorí pé omi ti wá títí dé ọkàn.+   Mo ti rì sínú ẹrẹ̀ jíjìn, níbi tí kò ti sí ilẹ̀ tí a lè dúró sí.+ Mo ti dé inú omi tí ó jìn dòò, Àní ìṣàn ti gbá mi lọ.+   Ó ti rẹ̀ mí nítorí kíké tí mo ń ké jáde;+ Ọ̀fun mi ti há. Ojú mi ti kọṣẹ́ bí mo ti ń dúró de Ọlọ́run mi.+   Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìí tilẹ̀ ti wá pọ̀ ju irun orí mi lọ.+ Àwọn tí ń pa mí lẹ́nu mọ́, tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá mi láìsí ìdí, ti di púpọ̀ níye.+ Ohun tí n kò fi ìjanilólè gbà ni mo wá ń dá padà.   Ọlọ́run, ìwọ alára ti wá mọ ìwà òmùgọ̀ mi, Ẹ̀bi mi kò sì pa mọ́ kúrò lójú rẹ.+   Kí ojú má ti àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ nítorí mi,+ Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.+ Kí a má ṣe tẹ́ àwọn tí ń wá ọ lógo nítorí mi,+ Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+   Nítorí pé mo ti ru ẹ̀gàn ní tìtorí rẹ,+ Ìtẹ́lógo ti bo ojú mi.+   Mo ti di ẹni tí àwọn arákùnrin mi kẹ̀yìn sí,+ Mo sì ti di ọmọ ilẹ̀ òkèèrè sí àwọn ọmọ ìyá mi.+   Nítorí pé ògédé ìtara fún ilé rẹ ti jẹ mí run,+ Àní ẹ̀gàn àwọn tí ń gàn ọ́ ti ṣubú lù mí.+ 10  Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún pẹ̀lú ààwẹ̀ gbígbà ọkàn mi,+ Ṣùgbọ́n ó wá jẹ́ ẹ̀gàn fún mi.+ 11  Nígbà tí mo fi aṣọ àpò ìdọ̀họ ṣe aṣọ mi, Mo wá di ẹni àfipòwe fún wọn.+ 12  Àwọn tí ó jókòó sí ẹnubodè bẹ̀rẹ̀ sí fún ọ̀ràn mi ní àfiyèsí,+ Èmi sì ni ẹṣin ọ̀rọ̀ orin àwọn tí ń mu ọtí tí ń pani.+ 13  Ṣùgbọ́n ní tèmi, Jèhófà, ìwọ ni mo ń gba àdúrà sí,+ Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, Ọlọ́run.+ Nínú ọ̀pọ̀ yanturu inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́, fi òtítọ́ ìgbàlà láti ọwọ́ rẹ dá mi lóhùn.+ 14  Dá mi nídè kúrò nínú ẹrẹ̀, kí n má bàa rì.+ Kí a dá mi nídè lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi+ àti kúrò nínú omi jíjìn.+ 15  Kí ìṣàn omi má ṣe gbá mi lọ,+ Tàbí kí ibú gbé mi mì, Tàbí kí kànga pa ẹnu rẹ̀ dé mọ́ mi.+ 16  Dá mi lóhùn, Jèhófà, nítorí pé inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ dára.+ Yí padà sí mi ní ìbámu pẹ̀lú ògìdìgbó àánú rẹ,+ 17  Má sì fi ojú rẹ pa mọ́ kúrò lára ìránṣẹ́ rẹ,+ Nítorí tí mo wà nínú hílàhílo, tètè dá mi lóhùn.+ 18  Sún mọ́ ọkàn mi, tún un gbà padà;+ Tún mi rà padà ní tìtorí àwọn ọ̀tá mi.+ 19  Ìwọ alára ti wá mọ ẹ̀gàn mi àti ìtìjú mi àti ìtẹ́lógo mi.+ Gbogbo àwọn tí ń fi ẹ̀tanú hàn sí mi wà ní iwájú rẹ.+ 20  Àní ẹ̀gàn ti ba ọkàn-àyà mi jẹ́, ọgbẹ́ náà sì jẹ́ aláìṣeéwòsàn.+ Mo sì ń retí ṣáá láti rí ẹnì kan tí yóò fi ìbánikẹ́dùn hàn, ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kankan;+ Àti láti rí àwọn olùtùnú, ṣùgbọ́n n kò rí ẹnì kankan.+ 21  Ṣùgbọ́n wọ́n fún mi ní ọ̀gbìn onímájèlé láti fi ṣe oúnjẹ,+ Àti fún òùngbẹ mi, wọ́n gbìyànjú láti mú mi mu ọtí kíkan.+ 22  Jẹ́ kí tábìlì wọn tí ó wà níwájú wọn di pańpẹ́,+ Kí ohun tí ó wà fún àlàáfíà wọn sì di ìdẹkùn.+ 23  Jẹ́ kí ojú wọn di èyí tí ó ṣókùnkùn kí wọ́n má lè ríran;+ Sì mú kí ìgbáròkó wọn pàápàá yẹ̀ nígbà gbogbo.+ 24  Da ìdálẹ́bi tí ó ti ọ̀dọ̀ rẹ wá sí wọn lórí,+ Kí ìbínú rẹ jíjófòfò sì dé bá wọn.+ 25  Jẹ́ kí ibùdó wọn tí a mọ ògiri yí ká di ahoro;+ Kí ó má ṣe sí olùgbé kankan nínú àgọ́ wọn.+ 26  Nítorí pé ẹni tí ìwọ tìkára rẹ kọlù ni wọ́n lépa,+ Ìrora àwọn tí o gún sì ni wọ́n ń ròyìn lẹ́sẹẹsẹ. 27  Fi ìṣìnà kún ìṣìnà wọn,+ Kí wọ́n má sì wá sínú òdodo rẹ.+ 28  Jẹ́ kí a nù wọ́n kúrò nínú ìwé àwọn alààyè,+ Kí a má sì kọrúkọ wọn mọ́ àwọn olódodo.+ 29  Ṣùgbọ́n a ń ṣẹ́ mi níṣẹ̀ẹ́, ara sì ń ro mí.+ Kí ìgbàlà rẹ dáàbò bò mí, Ọlọ́run.+ 30  Ṣe ni èmi yóò máa fi orin yin orúkọ Ọlọ́run,+ Èmi yóò sì fi ìdúpẹ́ gbé e ga lọ́lá.+ 31  Èyí yóò sì wu Jèhófà ju akọ màlúù,+ Ju ẹgbọrọ akọ màlúù tí ó ru ìwo sórí ṣaraṣara, èyí tí ó la pátákò.+ 32  Àwọn ọlọ́kàn tútù yóò rí i dájúdájú; wọn yóò máa yọ̀.+ Ẹ̀yin tí ń wá Ọlọ́run, kí ọkàn-àyà yín sì máa wà láàyè nìṣó.+ 33  Nítorí tí Jèhófà ń fetí sí àwọn òtòṣì,+ Ní tòótọ́, kì yóò sì tẹ́ńbẹ́lú àwọn ẹlẹ́wọ̀n tirẹ̀.+ 34  Kí ọ̀run àti ilẹ̀ ayé máa yìn ín,+ Àwọn òkun àti ohun gbogbo tí ń rìn kiri nínú wọn.+ 35  Nítorí tí Ọlọ́run tìkára rẹ̀ yóò gba Síónì là,+ Yóò sì kọ́ àwọn ìlú ńlá Júdà;+ Wọn yóò sì máa gbé níbẹ̀ dájúdájú, àwọn ni yóò sì ni ín.+ 36  Ọmọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni yóò sì jogún rẹ̀,+ Àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ orúkọ rẹ̀ ni yóò sì máa gbé inú rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé