Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 68:1-35

Sí olùdarí. Ti Dáfídì. Orin atunilára, orin. 68  Kí Ọlọ́run dìde,+ kí a tú àwọn ọ̀tá rẹ̀ ká,+ Kí àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ lọ́nà gbígbóná janjan sì sá lọ nítorí rẹ̀.+   Bí a ti ń fẹ́ èéfín lọ, bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ fẹ́ wọn lọ;+ Bí ìda ti ń yọ́ nítorí iná,+ Bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn ẹni burúkú ṣègbé kúrò níwájú Ọlọ́run.+   Ṣùgbọ́n ní ti àwọn olódodo, kí wọ́n máa yọ̀,+ Kí wọ́n kún fún ayọ̀ níwájú Ọlọ́run,+ Kí wọ́n sì máa yọ ayọ̀ ńláǹlà pẹ̀lú ayọ̀ yíyọ̀.+   Ẹ kọrin sí Ọlọ́run, ẹ kọ orin atunilára sí orúkọ rẹ̀;+ Ẹ gbé ohùn orin sókè sí Ẹni tí ń la àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀+ kọjá Gẹ́gẹ́ bí Jáà, tí í ṣe orúkọ rẹ̀;+ kí ẹ sì máa hó ìhó ayọ̀ níwájú rẹ̀;   Baba àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba àti onídàájọ́ fún àwọn opó+ Ni Ọlọ́run nínú ibùgbé rẹ̀ mímọ́.+   Ọlọ́run ń mú kí àwọn adánìkanwà máa gbé inú ilé;+ Ó ń mú àwọn ẹlẹ́wọ̀n jáde wá sínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ aásìkí.+ Bí ó ti wù kí ó rí, ní ti àwọn alágídí, ó dájú pé ilẹ̀ gbígbẹ ni wọn yóò máa gbé.+   Ọlọ́run, nígbà tí o jáde lọ níwájú àwọn ènìyàn rẹ,+ Nígbà tí o gba aṣálẹ̀ kọjá+Sélà—   Àní ilẹ̀ ayé mì jìgìjìgì,+ Ọ̀run pẹ̀lú kán tótó nítorí Ọlọ́run;+ Sínáì yìí mì jìgìjìgì nítorí Ọlọ́run,+ àní Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+   Ọ̀pọ̀ yanturu eji wọwọ ni o mú kí ó bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀, Ọlọ́run;+ Ogún rẹ, àní nígbà tí àárẹ̀ mú un—ìwọ tìkára rẹ fún un ní okun inú padà.+ 10  Àwùjọ àgọ́ rẹ+—wọ́n gbé inú rẹ̀;+ Nínú oore rẹ, Ọlọ́run, o tẹ̀ síwájú láti pèsè rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́.+ 11  Jèhófà tìkára rẹ̀ ni ó sọ àsọjáde náà;+ Àwọn obìnrin tí ń sọ ìhìn rere jẹ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ńlá.+ 12  Àní àwọn ọba àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun sá lọ, wọ́n sá lọ.+ Ní ti obìnrin tí ó wà ní ilé, ó ṣe àjọpín nínú ohun ìfiṣèjẹ.+ 13  Bí ẹ tilẹ̀ ń dùbúlẹ̀ sáàárín òkìtì eérú ibùdó, Ìyẹ́ apá àdàbà tí a fi fàdákà bò yóò wà, Àti ìyẹ́ rẹ̀ àfifò tí ó ní wúrà aláwọ̀ ewéko àdàpọ̀-mọ́-yẹ́lò.+ 14  Nígbà tí Olódùmarè tú àwọn ọba ká nínú rẹ̀,+ Ìrì dídì bẹ̀rẹ̀ sí sẹ̀ ní Sálímónì.+ 15  Ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Báṣánì+ jẹ́ òkè ńlá Ọlọ́run;+ Ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Báṣánì jẹ́ òkè ńlá tí ó ní àwọn téńté.+ 16  Èé ṣe tí ẹ̀yin òkè ńláńlá tí ó ní àwọn téńté fi ń fi ìlara wo Òkè ńlá tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ọkàn láti máa gbé inú rẹ̀?+ Àní Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò máa gbé ibẹ̀ títí láé.+ 17  Àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun Ọlọ́run jẹ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún mẹ́wàá-mẹ́wàá, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ní ìlọ́po ìlọ́po.+ Jèhófà tìkára rẹ̀ ti wá láti Sínáì sínú ibi mímọ́.+ 18  Ìwọ ti gòkè lọ sí ibi gíga lókè;+ Ìwọ ti kó àwọn òǹdè lọ;+ Ìwọ ti kó àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn,+ Bẹ́ẹ̀ ni, àní àwọn alágídí,+ láti máa gbé láàárín wọn,+ Jáà Ọlọ́run. 19  Ìbùkún ni fún Jèhófà, ẹni tí ń bá wa gbé ẹrù lójoojúmọ́,+ Ọlọ́run tòótọ́ ìgbàlà wa.+ Sélà. 20  Ọlọ́run tòótọ́ jẹ́ Ọlọ́run oníṣẹ́ ìgbàlà fún wa;+ Ti Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ+ sì ni àwọn ọ̀nà àbájáde kúrò lọ́wọ́ ikú.+ 21  Ní tòótọ́, Ọlọ́run tìkára rẹ̀ yóò fọ́ orí àwọn ọ̀tá rẹ̀ sí wẹ́wẹ́,+ Àní àtàrí onírun ti ẹnikẹ́ni tí ń rìn káàkiri nínú ẹ̀bi rẹ̀.+ 22  Jèhófà ti wí pé: “Èmi yóò mú wọn padà wá láti Báṣánì,+ Èmi yóò mú wọn padà wá láti inú ibú òkun,+ 23  Kí ìwọ lè wẹ ẹsẹ̀ rẹ nínú ẹ̀jẹ̀,+ Kí ahọ́n àwọn ajá rẹ lè ní ìpín tirẹ̀ láti ara àwọn ọ̀tá.”+ 24  Wọ́n ti rí ìtọ́wọ̀ọ́rìn rẹ, Ọlọ́run,+ Ìtọ́wọ̀ọ́rìn Ọlọ́run mi, Ọba mi, sínú ibi mímọ́.+ 25  Àwọn akọrin ń lọ níwájú, àwọn olùta ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín ń tọ̀ wọ́n lẹ́yìn;+ Àárín ni àwọn omidan tí ń lu ìlù tanboríìnì wà.+ 26  Ẹ fi ìbùkún fún Ọlọ́run nínú àpèjọpọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn,+ Fún Jèhófà ẹ̀yin tí ẹ ti Orísun Ísírẹ́lì wá.+ 27  Ibẹ̀ ni Bẹ́ńjámínì kékeré tí ó ń tẹ̀ wọ́n lórí ba wà,+ Àwọn ọmọ aládé Júdà pẹ̀lú ogunlọ́gọ̀ wọn tí ń kígbe, Àwọn ọmọ aládé Sébúlúnì, àwọn ọmọ aládé Náfútálì.+ 28  Ọlọ́run rẹ ti gbé àṣẹ kalẹ̀ fún okun rẹ.+ Fi okun hàn, Ọlọ́run, ìwọ tí o ti gbé ìgbésẹ̀ nítorí wa.+ 29  Nítorí tẹ́ńpìlì rẹ ní Jerúsálẹ́mù,+ Àwọn ọba yóò mú àwọn ẹ̀bùn wá fún ìwọ alára.+ 30  Bá ẹranko ẹhànnà tí ń bẹ nínú àwọn esùsú wí lọ́nà mímúná,+ àpéjọ àwọn akọ màlúù,+ Pẹ̀lú àwọn ọmọ màlúù àwọn ènìyàn, olúkúlùkù àwọn tí ń fi ẹsẹ̀ tẹ fàdákà mọ́lẹ̀.+ Ó ti tú àwọn ènìyàn tí ó ní inú dídùn sí ìjà ká.+ 31  Àwọn ohun tí a fi àdàlù bàbà àti tánganran ṣe yóò wá láti Íjíbítì;+ Kúṣì alára yóò tètè nawọ́ àwọn ẹ̀bùn sí Ọlọ́run.+ 32  Ẹ̀yin ìjọba ilẹ̀ ayé, ẹ kọrin sí Ọlọ́run,+ Ẹ kọ orin atunilára sí Jèhófà—Sélà 33  Sí Ẹni tí ń gun ọ̀run àwọn ọ̀run àtayébáyé.+ Sá wò ó! Ó fọ ohùn rẹ̀, ohùn líle.+ 34  Ẹ gbé okun fún Ọlọ́run.+ Orí Ísírẹ́lì ni ọlá ògo rẹ̀ wà, okun rẹ̀ sì wà nínú àwọsánmà.+ 35  Ọlọ́run jẹ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù láti inú ibùjọsìn rẹ títóbi lọ́lá.+ Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni ó jẹ́, ó ń fi okun fúnni, àní agbára ńlá fún àwọn ènìyàn.+ Ìbùkún ni fún Ọlọ́run.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé