Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 67:1-7

Sí olùdarí tí ń lo àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín. Orin atunilára, orin. 67  Ọlọ́run tìkára rẹ̀ yóò fi ojú rere hàn sí wa, yóò sì bù kún wa;+ Yóò mú kí ojú rẹ̀ tàn sára wa+Sélà—   Kí a lè mọ ọ̀nà rẹ ní ilẹ̀ ayé,+ Ìgbàlà rẹ àní láàárín gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.+   Kí àwọn ènìyàn gbé ọ lárugẹ, Ọlọ́run;+ Kí àwọn ènìyàn, gbogbo wọn, kí wọ́n gbé ọ lárugẹ.+   Kí àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè máa yọ̀, kí wọ́n sì máa fi ìdùnnú ké jáde,+ Nítorí tí ìwọ yóò fi ìdúróṣánṣán ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn;+ Àti ní ti àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè, ìwọ yóò máa ṣamọ̀nà wọn lórí ilẹ̀ ayé. Sélà.   Kí àwọn ènìyàn gbé ọ lárugẹ, Ọlọ́run;+ Kí àwọn ènìyàn, gbogbo wọn, kí wọ́n gbé ọ lárugẹ.+   Dájúdájú, ilẹ̀ ayé yóò máa mú èso rẹ̀ wá;+ Ọlọ́run, tí í ṣe Ọlọ́run wa, yóò bù kún wa.+   Ọlọ́run yóò bù kún wa,+ Gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò sì máa bẹ̀rù rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé