Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 66:1-20

Sí olùdarí. Orin, orin atunilára. 66  Ẹ fi ayọ̀ ìṣẹ́gun kígbe sí Ọlọ́run, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ ayé.+   Ẹ kọ orin atunilára sí ògo orúkọ rẹ̀.+ Ẹ ṣe ìyìn rẹ̀ ní ológo.+   Ẹ wí fún Ọlọ́run pé: “Àwọn iṣẹ́ rẹ mà ń múni kún fún ẹ̀rù o!+ Nítorí ọ̀pọ̀ yanturu okun rẹ, àwọn ọ̀tá rẹ yóò wá fi ìwárìrì tẹrí ba fún ọ.+   Gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ ayé yóò tẹrí ba fún ọ,+ Wọn yóò sì kọ orin atunilára sí ọ, wọn yóò kọ orin atunilára sí orúkọ rẹ.”+ Sélà.   Ẹ wá wo àwọn ìgbòkègbodò Ọlọ́run.+ Ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ènìyàn múni kún fún ẹ̀rù.+   Ó ti sọ òkun di ilẹ̀ gbígbẹ;+ Wọ́n fi ẹsẹ̀ sọdá odò.+ Ibẹ̀ ni a ti bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ nínú rẹ̀.+   Ó ń ṣàkóso nípa agbára ńlá rẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ Ojú rẹ̀ ń ṣọ́ àwọn orílẹ̀-èdè.+ Ní ti àwọn tí ó jẹ́ alágídí, kí a má ṣe gbé wọn ga nínú ara wọn.+ Sélà.   Ẹ fi ìbùkún fún Ọlọ́run wa,+ Ẹ sì mú kí a gbọ́ ohùn ìyìn sí i.+   Ó fi ọkàn wa múlẹ̀ nínú ìwàláàyè,+ Kò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.+ 10  Nítorí pé ìwọ ti wádìí wa wò, Ọlọ́run;+ Ìwọ ti yọ́ wa mọ́ bí ẹní ń yọ́ fàdákà mọ́.+ 11  Ìwọ ti mú wa wá sínú àwọ̀n tí a fi ń ṣọdẹ;+ Ìwọ ti gbé ìkìmọ́lẹ̀ ka ìgbáròkó wa. 12  Ìwọ ti mú kí ẹni kíkú gùn wá ní orí;+ A ti la iná àti omi kọjá,+ Ìwọ sì tẹ̀ síwájú láti mú wa jáde wá sínú ìtura.+ 13  Èmi yóò wá sínú ilé rẹ tèmi ti àwọn odindi ọrẹ ẹbọ sísun;+ Èmi yóò san àwọn ẹ̀jẹ́ mi fún ọ+ 14  Èyí tí mo la ètè mi láti jẹ́,+ Tí ẹnu mi sì sọ nígbà tí mo wà nínú hílàhílo.+ 15  Àwọn odindi ọrẹ ẹbọ sísun ti àwọn ẹran àbọ́pa ni èmi yóò fi rúbọ sí ọ,+ Pẹ̀lú èéfín ẹbọ ti àwọn àgbò. Èmi yóò fi akọ màlúù kan rúbọ pẹ̀lú àwọn òbúkọ.+ Sélà. 16  Ẹ wá, ẹ fetí sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, dájúdájú, èmi yóò sì ṣèròyìn+ Ohun tí ó ti ṣe fún ọkàn mi.+ 17  Èmi fi ẹnu mi ké pè é,+ Fífi ahọ́n mi kókìkí sì ṣẹlẹ̀.+ 18  Bí mo bá ti gbèrò ohun aṣenilọ́ṣẹ́ kankan nínú ọkàn-àyà mi, Jèhófà kì yóò gbọ́ mi.+ 19  Lóòótọ́, Ọlọ́run ti gbọ́;+ Ó ti fetí sí ohùn àdúrà mi.+ 20  Ìbùkún ni fún Ọlọ́run, ẹni tí kò ti àdúrà mi sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, Tí kò sì mú inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ kúrò lọ́dọ̀ mi.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé