Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 65:1-13

Sí olùdarí. Orin atunilára ti Dáfídì. Orin. 65  Ìyìn ń bẹ fún ọ—ìdákẹ́jẹ́ẹ́—, Ọlọ́run, ní Síónì;+ Ìwọ ni a ó sì san ẹ̀jẹ́ fún.+   Ìwọ Olùgbọ́ àdúrà, àní ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn ènìyàn ẹlẹ́ran ara gbogbo yóò wá.+   Àwọn nǹkan ìṣìnà ti já sí alágbára ńlá jù mí lọ.+ Ní ti àwọn ìrélànàkọjá wa, ìwọ tìkára rẹ yóò bò wọ́n.+   Aláyọ̀ ni ẹni tí ìwọ yàn, tí ìwọ sì mú kí ó tọ̀ ọ́ wá,+ Kí ó lè máa gbé inú àwọn àgbàlá rẹ.+ Dájúdájú, àwọn ohun rere inú ilé rẹ yóò tẹ́ wa lọ́rùn,+ Ibi mímọ́ tẹ́ńpìlì rẹ.+   Ìwọ yóò fi àwọn ohun amúnikún-fún-ẹ̀rù nínú òdodo dá wa lóhùn,+ Ìwọ Ọlọ́run ìgbàlà wa,+ Ìgbẹ́kẹ̀lé gbogbo ojú ààlà ilẹ̀ ayé àti àwọn tí ó jìnnà réré lójú òkun.+   Ó fi àwọn òkè ńláńlá múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in nípasẹ̀ agbára rẹ̀;+ Ó fi agbára ńlá di àmùrè ní tòótọ́.+   Ó ń mú ariwo àwọn òkun pa rọ́rọ́,+ Ariwo ìgbì wọn àti yánpọnyánrin àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè.+   Àwọn olùgbé apá ìkángun pátápátá yóò sì fòyà àwọn iṣẹ́ àmì rẹ;+ Ìwọ ń mú kí ìjáde lọ òwúrọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ kí ó máa fi ìdùnnú ké jáde.+   Ìwọ ti yí àfiyèsí rẹ sí ilẹ̀ ayé, kí o lè fún un ní ọ̀pọ̀ yanturu;+ Ìwọ sọ ọ́ di ọlọ́rọ̀ gidigidi. Ìṣàn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kún fún omi.+ Ìwọ ti pèsè ọkà wọn sílẹ̀,+ Nítorí pé bí ìwọ ṣe pèsè ilẹ̀ ayé sílẹ̀ nìyẹn.+ 10  Fífi omi rin aporo rẹ̀ gbingbin wáyé, àti mímú ògúlùtu rẹ̀ tẹ́jú;+ Ìwọ fi ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀wààrà òjò mú un dẹ̀; ìwọ bù kún èéhù rẹ̀ pàápàá.+ 11  Ìwọ ti fi oore rẹ dé ọdún ládé,+ Ọ̀rá sì ń kán tótó àní ní àwọn òpó ọ̀nà rẹ.+ 12  Àwọn ilẹ̀ ìjẹko tí ń bẹ ní aginjù ń kán tótó,+ Àní àwọn òkè kéékèèké sì fi ìdùnnú di ara wọn lámùrè.+ 13  Àwọn pápá ìjẹko ni a ti fi àwọn agbo ẹran bò,+ Àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ni a sì fi ọkà bò kanlẹ̀.+ Wọ́n ń kígbe nínú ayọ̀ ìṣẹ́gun, bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n ń kọrin.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé