Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 63:1-11

Orin atunilára ti Dáfídì, nígbà tí ó wà ní aginjù Júdà.+ 63  Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run mi, mo ń wá ọ ṣáá.+ Òùngbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi.+ Àárẹ̀ ti mú ẹran ara mi nítorí ìyánhànhàn fún ọ Ní ilẹ̀ tí ó gbẹ tí ó sì rí táútáú, níbi tí omi kò sí.+   Bí mo ṣe rí ọ nìyẹn nínú ibi mímọ́,+ Nígbà tí mo rí okun rẹ àti ògo rẹ.+   Nítorí pé inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ sàn ju ìyè,+ Ètè mi yóò gbóríyìn fún ọ.+   Bí èmi yóò ṣe máa fi ìbùkún fún ọ nìyẹn ní ìgbà ayé mi;+ Èmi yóò máa gbé àtẹ́lẹwọ́ mi sókè ní orúkọ rẹ.+   Bí ẹni pé pẹ̀lú apá tí ó dára jù lọ, àní ọ̀rá, ọkàn mi ni a tẹ́ lọ́rùn,+ Ètè tí ó kún fún igbe ìdùnnú sì ni ẹnu mi fi ń mú ìyìn wá.+   Nígbà tí mo rántí rẹ lórí àga ìrọ̀gbọ̀kú gbọọrọ mi,+ Mo ń ṣe àṣàrò nípa rẹ ní àwọn ìṣọ́ òru.+   Nítorí pé ìwọ ti já sí ìrànwọ́ fún mi,+ Mo sì ń fi ìdùnnú ké jáde nínú òjìji ìyẹ́ apá rẹ.+   Ọkàn mi ti tẹ̀ lé ọ pẹ́kípẹ́kí;+ Ọwọ́ ọ̀tún rẹ dì mí mú ṣinṣin.+   Ní ti àwọn tí ń wá ọkàn mi ṣáá láti pa á run,+ Wọn yóò wá sí ibi rírẹlẹ̀ jù lọ ní ilẹ̀ ayé.+ 10  A ó fà wọ́n lé agbára idà lọ́wọ́;+ Wọn yóò di ìpín lásán-làsàn fún àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀.+ 11  Ọba tìkára rẹ̀ yóò sì máa yọ̀ nínú Ọlọ́run.+ Olúkúlùkù ẹni tí ń fi í búra yóò máa ṣògo,+ Nítorí pé ẹnu àwọn tí ń ṣèké ni a óò mú dákẹ́ fẹ́mú.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé