Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 62:1-12

Sí olùdarí Jédútúnì. Orin atunilára ti Dáfídì. 62  Ní tòótọ́, Ọlọ́run ni ọkàn mi ń dúró dè ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́.+ Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá ni ìgbàlà mi.+   Ní tòótọ́, òun ni àpáta mi àti ìgbàlà mi, ibi gíga ààbò mi;+ A kì yóò mú kí n ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n púpọ̀ jù.+   Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ óò máa bá a lọ ní ṣíṣe kìtàkìtà sí ẹni tí ẹ ó ṣìkà pa?+ Gbogbo yín dà bí ògiri títẹ̀, ògiri òkúta tí ń tẹ̀ wọnú lọ.+   Ní tòótọ́, wọ́n ń fúnni ní àmọ̀ràn láti lè dẹni lọ kúrò nínú iyì ẹni;+ Wọ́n ní ìdùnnú nínú irọ́.+ Wọ́n ń fi ẹnu wọn súre, ṣùgbọ́n nínú, wọ́n ń pe ibi wá síni lórí.+ Sélà.   Ní tòótọ́, fi ìdákẹ́jẹ́ẹ́ dúró de Ọlọ́run, ìwọ ọkàn mi,+ Nítorí pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí mi ti wá.+   Ní tòótọ́, òun ni àpáta mi àti ìgbàlà mi, ibi gíga ààbò mi;+ A kì yóò mú kí n ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.+   Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi àti ògo mi wà.+ Àpáta lílágbára mi, ibi ìsádi mi wà nínú Ọlọ́run.+   Ẹ gbẹ́kẹ̀ lé e ní gbogbo ìgbà.+ Ẹ tú ọkàn-àyà yín jáde níwájú rẹ̀.+ Ọlọ́run jẹ́ ibi ìsádi fún wa.+ Sélà.   Ní tòótọ́, èémí àmíjáde ni àwọn ọmọ ará ayé,+ Irọ́ ni àwọn ọmọ aráyé.+ Nígbà tí a bá gbé wọn lé òṣùwọ̀n, gbogbo wọn lápapọ̀ fúyẹ́ ju èémí àmíjáde.+ 10  Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé jìbìtì lílù,+ Tàbí kí ẹ di asán nínú olè jíjà paraku.+ Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àlùmọ́ọ́nì ìgbọ́bùkátà ń gbèrú, ẹ má ṣe gbé ọkàn-àyà yín lé e.+ 11  Ẹ̀ẹ̀kan ni Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀, ẹ̀ẹ̀mejì sì ni mo ti gbọ́ èyí pàápàá,+ Pé ti Ọlọ́run ni okun.+ 12  Pẹ̀lúpẹ̀lù, tìrẹ ni inú-rere-onífẹ̀ẹ́, Jèhófà,+ Nítorí tí ìwọ tìkára rẹ ń san án padà fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé