Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 61:1-8

Sí olùdarí tí ń lo àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín. Ti Dáfídì. 61  Gbọ́ igbe ìpàrọwà mi, Ọlọ́run.+ Fetí sí àdúrà mi.+   Èmi yóò kígbe láti ìkángun ilẹ̀ ayé, àní sí ọ, nígbà tí ọkàn-àyà mi bá di ahẹrẹpẹ.+ Kí o ṣamọ̀nà mi lọ sórí àpáta tí ó ga jù mí.+   Nítorí pé o ti jẹ́ ibi ìsádi fún mi,+ Ilé gogoro lílágbára ní ojú ọ̀tá.+   Dájúdájú, èmi yóò jẹ́ àlejò nínú àgọ́ rẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin;+ Èmi yóò sá di ibi ìlùmọ́ ìyẹ́ apá rẹ.+ Sélà.   Nítorí pé ìwọ fúnra rẹ, Ọlọ́run, ti fetí sí àwọn ẹ̀jẹ́ mi.+ O ti fún mi ní ohun ìní àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ.+   Ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni ìwọ yóò fi kún àwọn ọjọ́ ọba;+ Àwọn ọdún rẹ̀ yóò dà bí ìran dé ìran.+   Òun yóò máa gbé fún àkókò tí ó lọ kánrin níwájú Ọlọ́run;+ Fún un ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òótọ́, kí ìwọ̀nyí lè máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ.+   Ó dájú pé báyìí ni èmi yóò máa kọ orin atunilára sí orúkọ rẹ títí láé,+ Kí n lè san àwọn ẹ̀jẹ́ mi ní ọjọ́ dé ọjọ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé