Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 60:1-12

Sí olùdarí lórí Òdòdó Lílì Ìránnilétí. Míkítámù. Ti Dáfídì. Fún kíkọ́ni.+ Nígbà tí ó kó wọnú ìjàkadì pẹ̀lú Aramu-náháráímù àti Aramu-Sóbà, tí Jóábù sì tẹ̀ síwájú láti padà lọ ṣá Édómù balẹ̀ ní Àfonífojì Iyọ̀, àní ẹgbẹ̀rún méjìlá.+ 60  Ọlọ́run, o ti ta wá nù, o ti ya lù wá,+ Ìbínú rẹ ti ru sókè. Ó yẹ kí o mú wa padà bọ̀ sípò.+   O ti mú kí ilẹ̀ ayé mì jìgìjìgì, o ti là á sọ́tọ̀ọ̀tọ̀,+ Wo àlàfo rẹ̀ sàn, nítorí pé ó ti ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.+   O ti jẹ́ kí àwọn ènìyàn rẹ rí ìnira.+ O ti mú kí a mu wáìnì tí ń mú wa ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́.+   O ti fi àmì àfiyèsí fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ+ Láti máa sá sọ́tùn-ún sósì ní tìtorí ọrun. Sélà.   Kí a lè gba àwọn olùfẹ́ rẹ ọ̀wọ́n sílẹ̀,+ Fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ìgbàlà, kí o sì dá wa lóhùn.+   Ọlọ́run tìkára rẹ̀ ti sọ̀rọ̀ nínú ìjẹ́mímọ́+ rẹ̀ pé: “Ṣe ni èmi yóò máa yọ ayọ̀ ńláǹlà, ṣe ni èmi yóò fi Ṣékémù fúnni gẹ́gẹ́ bí ìpín;+ Èmi yóò sì díwọ̀n pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ Súkótù.+   Gílíádì jẹ́ tèmi, Mánásè sì jẹ́ tèmi,+ Éfúráímù sì ni odi agbára ẹni tí mo fi ṣe olórí; Júdà ni ọ̀pá àṣẹ mi.+   Móábù ni ìkòkò tí mo fi ń fọ nǹkan.+ Orí Édómù ni èmi yóò sọ sálúbàtà mi sí.+ Lórí Filísíà ni èmi yóò kígbe nínú ayọ̀ ìṣẹ́gun.”+   Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú ńlá tí a sàga tì?+ Ta ni yóò ṣamọ̀nà mi dájúdájú títí dé Édómù?+ 10  Kì í ha ṣe ìwọ, Ọlọ́run, ẹni tí ó ti ta wá nù,+ Tí kò sì bá àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa jáde lọ bí Ọlọ́run?+ 11  Fún wa ní ìrànwọ́ kúrò nínú wàhálà,+ Níwọ̀n bí ìgbàlà nípasẹ̀ ará ayé kò ti ní láárí.+ 12  Nípasẹ̀ Ọlọ́run ni àwa yóò jèrè ìmí,+ Òun fúnra rẹ̀ yóò sì tẹ àwọn elénìní wa mọ́lẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé