Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 6:1-10

Sí olùdarí tí ń lo àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín lórí ọ́kítéfì ìsàlẹ̀.+ Orin atunilára ti Dáfídì. 6  Jèhófà, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ,+ Má sì ṣe tọ́ mi sọ́nà nínú ìhónú rẹ.+   Fi ojú rere hàn sí mi, Jèhófà, nítorí pé okun mi ń tán lọ.+ Mú mi lára dá,+ Jèhófà, nítorí pé a ti yọ egungun mi lẹ́nu.   Bẹ́ẹ̀ ni, a ti yọ ọkàn mi lẹ́nu gidigidi;+ Àti ìwọ, Jèhófà—yóò ti pẹ́ tó?+   Padà,+ Jèhófà, gba ọkàn mi sílẹ̀;+ Gbà mí là nítorí inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́.+   Nítorí tí kò sí mímẹ́nukàn ọ́ nínú ikú;+ Nínú Ṣìọ́ọ̀lù, ta ni yóò gbé ọ lárugẹ?+   Agara ìmí ẹ̀dùn mi ti dá mi;+ Láti òru mọ́jú ni mo ń mú kí àga ìrọ̀gbọ̀kú mi rin gbingbin;+ Omijé mi ni mo fi ń mú kí àga ìnàyìn mi kún àkúnwọ́sílẹ̀.+   Ìbìnújẹ́ ti sọ ojú mi di aláìlera,+ Ó ti di ogbó nítorí gbogbo àwọn tí ń fi ẹ̀tanú hàn sí mi.+   Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin aṣenilọ́ṣẹ́,+ Nítorí pé Jèhófà yóò gbọ́ ìró ẹkún mi dájúdájú.+   Ní tòótọ́, Jèhófà yóò gbọ́ ìbéèrè mi fún ojú rere;+ Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gba àdúrà tèmi.+ 10  Ojú yóò ti+ gbogbo àwọn ọ̀tá mi, a ó sì yọ wọ́n lẹ́nu gan-an; Wọn yóò yí padà, ojú yóò tì wọ́n lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé