Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 59:1-17

Sí olùdarí. “Má ṣe run ún.” Ti Dáfídì. Míkítámù. Nígbà tí Sọ́ọ̀lù ránṣẹ́, tí wọ́n sì ń ṣọ́ ilé, láti fi ikú pa á.+ 59  Dá mi nídè lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, ìwọ Ọlọ́run mi;+Kí o dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn tí ń dìde sí mi.+   Dá mi nídè lọ́wọ́ àwọn aṣenilọ́ṣẹ́,+Kí o sì gbà mí là lọ́wọ́ àwọn ajẹ̀bi ẹ̀jẹ̀.   Nítorí, wò ó! wọ́n ti lúgọ de ọkàn mi;+Àwọn alágbára gbéjà kò mí,+Láìsí ìdìtẹ̀ kankan níhà ọ̀dọ̀ mi, tàbí ẹ̀ṣẹ̀ èyíkéyìí níhà ọ̀dọ̀ mi, Jèhófà.+   Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ìṣìnà kankan, wọ́n sáré, wọ́n sì múra sílẹ̀.+Ta jí sí pípè mi, kí o sì rí i.+   Ìwọ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun sì ni Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+Jí láti yí àfiyèsí rẹ sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.+Má fi ojú rere hàn sí ọ̀dàlẹ̀ èyíkéyìí tí ó jẹ́ aṣenilọ́ṣẹ́.+ Sélà.   Wọ́n ń padà wá ṣáá ní àṣálẹ́;+Wọ́n ń gbó ṣáá bí ajá,+ wọ́n sì ń lọ yí ká ìlú ńlá náà.+   Wò ó! Wọ́n ń fi ẹnu wọn ṣe ìtújáde;+Àwọn idà wà ní ètè wọn,+Nítorí pé ta ni ó ń fetí sílẹ̀?+   Ṣùgbọ́n ìwọ fúnra rẹ, Jèhófà, yóò fi wọ́n rẹ́rìn-ín;+Ìwọ yóò fi gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ṣẹ̀sín.+   Ìwọ Okun mi, ìwọ ni èmi yóò máa wò;+Nítorí pé Ọlọ́run ni ibi gíga ààbò mi.+ 10  Ọlọ́run tí ń ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí mi yóò fúnra rẹ̀ kò mí lójú;+Ọlọ́run tìkára rẹ̀ yóò mú mi wo àwọn ọ̀tá mi.+ 11  Má pa wọ́n, kí àwọn ènìyàn mi má bàa gbàgbé.+Nípasẹ̀ ìmí rẹ, mú kí wọ́n máa rìn gbéregbère,+Kí o sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, ìwọ Jèhófà apata wa,+ 12  Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ẹnu wọn, àní ọ̀rọ̀ ètè wọn;+Kí a sì mú wọn nínú ìgbéraga wọn,+Àní nítorí ègún àti ẹ̀tàn tí wọ́n ń sọ ní àsọtúnsọ. 13  Mú wọn wá sí òpin nínú ìhónú;+Mú wọn wá sí òpin, kí wọ́n má bàa sí mọ́;Kí wọ́n sì mọ̀ pé Ọlọ́run ń ṣàkóso nínú Jékọ́bù títí dé òpin ilẹ̀ ayé.+ Sélà. 14  Sì jẹ́ kí wọ́n padà wá ní àṣálẹ́;Jẹ́ kí wọ́n máa gbó bí ajá, kí wọ́n sì lọ yí ká ìlú ńlá.+ 15  Jẹ́ kí àwọn wọ̀nyí gan-an máa rìn gbéregbère wá ohun jíjẹ kiri;+Má ṣe jẹ́ kí wọ́n yó tàbí kí wọ́n sùn mọ́jú.+ 16  Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi yóò máa kọrin nípa okun rẹ,+Àti ní òwúrọ̀, èmi yóò máa fi ìdùnnú sọ̀rọ̀ nípa inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́.+Nítorí pé ìwọ ti jẹ́ ibi gíga ààbò fún mi+Àti ibi ìsásí ní ọjọ́ wàhálà mi.+ 17  Ìwọ Okun mi, ìwọ ni èmi yóò máa kọ orin atunilára sí,+Nítorí pé Ọlọ́run ni ibi gíga ààbò mi, Ọlọ́run tí ń ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí mi.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé