Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 58:1-11

Sí olùdarí. “Má ṣe run ún.” Ti Dáfídì. Míkítámù. 58  Nínú ìdákẹ́jẹ́ẹ́ yín, ẹ ha lè sọ̀rọ̀ nípa òdodo ní ti tòótọ́ bí?+Ẹ ha lè ṣe ìdájọ́ nínú ìdúróṣánṣán bí, ẹ̀yin ọmọ ènìyàn?+   Kàkà bẹ́ẹ̀, mélòómélòó ni ẹ ń fi ọkàn-àyà ṣe àìṣòdodo paraku ní ilẹ̀ ayé,+Tí ẹ sì ń palẹ̀ ọ̀nà mọ́, àní fún ìwà ipá ọwọ́ yín!+   Àwọn ẹni burúkú ti jẹ́ aláyìídáyidà láti inú ilé ọlẹ̀ wá;+Láti ìgbà tí wọ́n ti wà nínú ikùn ni wọ́n ti ń rìn gbéregbère;Wọ́n ń purọ́.+   Oró wọ́n dà bí oró ejò,+Wọ́n jẹ́ adití bí ṣèbé tí ń di etí rẹ̀,+   Tí kì í fetí sí ohùn àwọn atujú,+Bí ẹni tí ó gbọ́n tilẹ̀ ń lo èèdì.+   Ọlọ́run, gbá eyín wọn yọ lẹ́nu wọn.+Àní kí o fọ́ egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ àwọn ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ túútúú, Jèhófà.   Kí wọ́n yọ́ bí ẹni pé sínú omi tí ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ;+Kí ó fa ọrun fún àwọn ọfà rẹ̀ bí wọ́n ti ń wó lulẹ̀.+   Ó ń rìn bí ìgbín tí ń yọ́ dànù;Bí ìṣẹ́nú obìnrin, ó dájú pé wọn kì yóò rí oòrùn.+   Kí àwọn ìkòkò yín tó mọ igi ẹlẹ́gún+ tí ń jó lára,Ààyè ewéko àti èyí tí ń jó, òun yóò gbé wọn lọ bí ẹ̀fúùfù oníjì.+ 10  Olódodo yóò máa yọ̀ nítorí pé ó ti rí ẹ̀san.+Yóò fi ẹ̀jẹ̀ ẹni burúkú wẹ àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀.+ 11  Aráyé yóò sì sọ pé:+ “Dájúdájú, èso ń bẹ fún olódodo.+Dájúdájú, Ọlọ́run kan wà tí ń ṣe ìdájọ́ ní ilẹ̀ ayé.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé