Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 57:1-11

Sí olùdarí. “Má ṣe run ún.” Ti Dáfídì. Míkítámù. Nígbà tí ó fẹsẹ̀ fẹ nítorí Sọ́ọ̀lù, tí ó sì lọ sínú hòrò.+ 57  Fi ojú rere hàn sí mi, Ọlọ́run, fi ojú rere hàn sí mi,+ Nítorí pé ìwọ ni ọkàn mi sá di;+ Òjìji ìyẹ́ apá rẹ sì ni mo sá di títí àwọn àgbákò fi ré kọjá.+   Mo ké pe Ọlọ́run tí í ṣe Ẹni Gíga Jù Lọ, mo ké pe Ọlọ́run tòótọ́ tí ń mú wọn wá sí òpin ní tìtorí mi.+   Yóò ránṣẹ́ láti ọ̀run wá, yóò sì gbà mí là.+ Dájúdájú, òun yóò kó ìdàrúdàpọ̀ bá ẹni tí ń kù gìrì mọ́ mi.+ Sélà. Ọlọ́run yóò fi inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ àti òótọ́ rẹ̀ ránṣẹ́.+   Ọkàn mi wà ní àárín àwọn kìnnìún;+ Èmi kò lè ṣàìdùbúlẹ̀ sáàárín àwọn ajẹnirun, àní àwọn ọmọ ènìyàn, Àwọn tí eyín wọ́n jẹ́ ọ̀kọ̀ àti ọfà,+ Tí ahọ́n wọ́n sì jẹ́ idà mímú.+   Kí a gbé ọ ga lékè ọ̀run, Ọlọ́run;+ Kí ògo rẹ wà lókè gbogbo ilẹ̀ ayé.+   Àwọ̀n ni wọ́n ti dẹ sílẹ̀ de àwọn ìṣísẹ̀ mi;+ Ọkàn mi ti tẹ̀ ba.+ Wọ́n wa ọ̀fìn síwájú mi; Wọ́n ti jìn sí àárín rẹ̀.+ Sélà.   Ọkàn-àyà mi fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, Ọlọ́run,+ Ọkàn-àyà mi fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin. Ṣe ni èmi yóò máa kọrin, tí èmi yóò sì máa kọ orin atunilára.+   Jí, ìwọ ògo mi;+ Jí, ìwọ ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín; àti ìwọ náà, háàpù,+ Ṣe ni èmi yóò jí ọ̀yẹ̀.   Èmi yóò máa gbé ọ lárugẹ láàárín àwọn ènìyàn, Jèhófà;+ Èmi yóò máa kọ orin atunilára sí ọ láàárín àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè.+ 10  Nítorí tí inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ga títí dé ọ̀run,+ Àti òótọ́ rẹ títí dé sánmà.+ 11  Kí a gbé ọ ga lékè ọ̀run, Ọlọ́run;+ Kí ògo rẹ wà lókè gbogbo ilẹ̀ ayé.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé