Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 56:1-13

Sí olùdarí lórí Àdàbà Tí Ó Dákẹ́ Jẹ́ẹ́ láàárín àwọn tí ó jìnnà réré. Ti Dáfídì. Míkítámù. Nígbà tí àwọn Filísínì gbá a mú ní Gátì.+ 56  Fi ojú rere hàn sí mi, Ọlọ́run, nítorí pé ẹni kíkú ti kù gìrì mọ́ mi.+ Ní jíjagun láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀, ó ń ni mí lára ṣáá.+   Àwọn ọ̀tá mi ń kù gìrì mọ́ mi ṣáá láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀,+ Nítorí pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ń fi ọkàn gíga bá mi jagun.+   Ọjọ́kọ́jọ́ tí àyà bá ń fò mí, èmi, ní tèmi, yóò gbẹ́kẹ̀ lé ìwọ gan-an.+   Ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run ni èmi yóò máa yin ọ̀rọ̀ rẹ̀.+ Ọlọ́run ni mo gbẹ́kẹ̀ lé; àyà kì yóò fò mí.+ Kí ni ẹlẹ́ran ara lè fi mí ṣe?+   Láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ ni wọ́n ń ṣe àwọn àlámọ̀rí tèmi lọ́ṣẹ́; Gbogbo ìrònú wọn ni ó lòdì sí mi fún búburú.+   Wọ́n gbéjà kò mí, wọ́n fara pa mọ́,+ Àwọn, ní tiwọn, ń ṣàkíyèsí àwọn ìṣísẹ̀ tèmi gan-an,+ Bí wọ́n ti dúró de ọkàn mi.+   Ní tìtorí ìṣenilọ́ṣẹ́ wọn, ta wọ́n nù.+ Nínú ìbínú, kí o rẹ àwọn ènìyàn náà pàápàá sílẹ̀, Ọlọ́run.+   Jíjẹ́ tí mo jẹ́ ìsáǹsá ni ìwọ alára ti ròyìn.+ Fi omijé mi sínú ìgò awọ rẹ.+ Wọn kò ha sí nínú ìwé rẹ?+   Ní àkókò yẹn, àwọn ọ̀tá mi yóò yí padà, ní ọjọ́ tí mo bá pè;+ Èyí ni èmi mọ̀ dáadáa, pé Ọlọ́run wà fún mi.+ 10  Ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run+ ni èmi yóò máa yin ọ̀rọ̀ rẹ̀; Ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Jèhófà ni èmi yóò máa yin ọ̀rọ̀ rẹ̀.+ 11  Ọlọ́run ni mo gbẹ́kẹ̀ lé, àyà kì yóò fò mí.+ Kí ni ará ayé lè fi mí ṣe?+ 12  Àwọn ẹ̀jẹ́ ń bẹ lọ́rùn mi fún ọ, Ọlọ́run.+ Èmi yóò máa fi ọpẹ́ hàn fún ọ.+ 13  Nítorí pé ìwọ ti dá ọkàn mi nídè lọ́wọ́ ikú+ Ìwọ kò ha ti dá ẹsẹ̀ mi nídè kúrò nínú ìkọ̀sẹ̀?+ Kí n lè máa rìn káàkiri níwájú Ọlọ́run nínú ìmọ́lẹ̀ àwọn tí ó wà láàyè.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé