Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 55:1-23

Sí olùdarí tí ń lo àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín. Másíkílì. Ti Dáfídì. 55  Fi etí sí àdúrà mi, Ọlọ́run;+Má sì fi ara rẹ pa mọ́ fún ìbéèrè mi fún ojú rere.+   Fiyè sí mi, kí o sì dá mi lóhùn.+Ìdàníyàn mi ti sọ mí di aláìlègbéjẹ́ẹ́,+Èmi kò sì lè ṣàìfi àìbalẹ̀-ọkàn hàn,ìpinn   Ní tìtorí ohùn ọ̀tá, nítorí ìdaniláàmú ẹni burúkú.+Nítorí pé wọ́n ń da ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́ lù mí ṣáá,+Wọ́n sì ń fi ìbínú ṣe kèéta sí mi.+   Àní ọkàn-àyà mi ń jẹ ìrora mímúná nínú mi,+Jìnnìjìnnì ikú pàápàá sì ti já lù mí.+   Ìbẹ̀rù, bẹ́ẹ̀ ni, àní ìwárìrì wọnú mi,+Ìgbọ̀njìnnìjìnnì sì bò mí.   Mo sì ń wí pé: “Ì bá ṣe pé mo ní ìyẹ́ apá bí ti àdàbà!+Èmi ì bá fò lọ, èmi ì bá sì máa gbé ní ibòmíràn.+   Wò ó! Èmi ì bá fò lọ jìnnà réré;+Èmi ì bá wọ̀ sí aginjù.+Sélà—   Èmi ì bá ṣe kánkán lọ sí ibi àsálà miKúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù tí ń rọ́ yìì, kúrò lọ́wọ́ ìjì líle.”+   Dà wọ́n rú, Jèhófà, pín ahọ́n wọn níyà,+Nítorí pé mo ti rí ìwà ipá àti awuyewuye nínú ìlú ńlá náà.+ 10  Tọ̀sán-tòru ni wọ́n ń yí i po lórí ògiri rẹ̀;+Ọṣẹ́ àti ìjàngbọ̀n sì ń bẹ nínú rẹ̀.+ 11  Àgbákò ń bẹ nínú rẹ̀;Ìnilára àti ẹ̀tàn kò sì ṣí kúrò ní ojúde rẹ̀.+ 12  Nítorí pé kì í ṣe ọ̀tá ni ó bẹ̀rẹ̀ sí gàn mí;+Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, èmi ì bá fara dà á.Kì í ṣe ẹni tí ó kórìíra mi lọ́nà gbígbóná janjan ni ó gbé àgbéré ńláǹlà sí mi;+Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, èmi ì bá fi ara mi pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.+ 13  Ṣùgbón ìwọ ni, ẹni kíkú tí ó jẹ́ bí ọgbọọgba pẹ̀lú mi,+Ẹni tí mo mọ̀ dunjú àti ojúlùmọ̀ mi,+ 14  Nítorí pé a máa ń gbádùn ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ aládùn pa pọ̀ tẹ́lẹ̀ rí;+A máa ń bá ọ̀pọ̀ ènìyàn rìn lọ sí ilé Ọlọ́run tẹ́lẹ̀ rí.+ 15  Kí ìsọdahoro dé bá wọn!+Kí wọ́n sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú Ṣìọ́ọ̀lù láàyè;+Nítorí pé nígbà tí wọ́n ń ṣe àtìpó ni àwọn nǹkan búburú ti wà nínú wọn.+ 16  Ní tèmi, Ọlọ́run ni èmi yóò ké pè;+Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò sì gbà mí là.+ 17  Alẹ́ àti òwúrọ̀ àti ìgbà ọ̀sán gangan, èmi kò lè ṣàìfi ìdàníyàn hàn, kí n sì máa kédàárò,+Ó sì ń gbọ́ ohùn mi.+ 18  Dájúdájú, yóò tún mi rà padà, yóò sì fi ọkàn mi sínú àlàáfíà kúrò nínú ìjà tí ó bá mi,+Nítorí pé ní ògìdìgbó púpọ̀ ni wọ́n wá gbéjà kò mí.+ 19  Ọlọ́run yóò gbọ́, yóò sì dá wọn lóhùn,+Àní Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ bí ti ìgbà tí ó ti kọjá+Sélà—Àwọn tí kò sí ìyípadà kankan lọ́dọ̀ wọn+Àti àwọn tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run.+ 20  Ó ti na ọwọ́ rẹ̀ jáde lòdì sí àwọn tí ó wà ní àlàáfíà pẹ̀lú rẹ̀;+Ó ti sọ májẹ̀mú rẹ̀ di aláìmọ́.+ 21  Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ jọ̀lọ̀ ju bọ́tà,+Ṣùgbọ́n ọkàn-àyà rẹ̀ ti ṣe tán láti jà.+Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ tuni lára ju òróró,+Ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ idà tí a fà yọ.+ 22  Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀,+Òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró.+Kì yóò jẹ́ kí olódodo ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.+ 23  Ṣùgbọn ìwọ fúnra rẹ, Ọlọ́run, yóò mú wọn sọ̀ kalẹ̀ lọ sí kòtò rírẹlẹ̀ jù lọ.+Ní ti àwọn ajẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ àti ẹlẹ́tàn, wọn kì yóò gbé ààbọ̀ iye ọjọ́ wọn.+Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi yóò gbẹ́kẹ̀ lé ọ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé