Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 54:1-7

Sí olùdarí tí ń lo àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín. Másíkílì. Ti Dáfídì. Nígbà tí àwọn ọmọ Sífù wọlé wá, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Dáfídì kò ha fi ara rẹ̀ pa mọ́ sọ́dọ̀ wa?”+ 54  Ọlọ́run, gbà mí là nípa orúkọ rẹ,+Sì fi agbára ńlá rẹ gba ẹjọ́ mi rò.+   Ọlọ́run, gbọ́ àdúrà mi;+Fi etí sí àwọn àsọjáde ẹnu mi.+   Nítorí tí àwọn àjèjì wà tí ó ti dìde sí mi,Àti àwọn afìkà-gboni-mọ́lẹ̀ tí ń wá ọkàn mi.+Wọn kò gbé Ọlọ́run ka iwájú wọn.+ Sélà.   Wò ó! Ọlọ́run ni olùrànlọ́wọ́ mi;+Jèhófà wà lára àwọn tí ń ti ọkàn mi lẹ́yìn.   Òun yóò san búburú padà fún àwọn ọ̀tá mi;+Pa wọ́n lẹ́nu mọ́ nínú òótọ́ rẹ.+   Tinútinú ni èmi yóò fi rúbọ sí ọ.+Èmi yóò máa gbé orúkọ rẹ lárugẹ, Jèhófà, nítorí tí ó dára.+   Nítorí tí ó dá mi nídè kúrò nínú gbogbo wàhálà,+Ojú mi sì wo àwọn ọ̀tá mi.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé