Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 53:1-6

Sí olùdarí lórí Máhálátì.+ Másíkílì. Ti Dáfídì. 53  Òpònú sọ nínú ọkàn-àyà rẹ̀ pé:“Jèhófà kò sí.”+Wọ́n ti gbé ìgbésẹ̀ tí ń fa ìparun, wọ́n sì ti hùwà lọ́nà ìṣe-họ́ọ̀-sí nínú àìṣòdodo;+Kò sí ẹni tí ń ṣe rere.+   Ní ti Ọlọ́run, ó bojú wolẹ̀ láti ọ̀run wo àwọn ọmọ ènìyàn,+Láti rí i bóyá ẹnikẹ́ni wà tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye, ẹnikẹ́ni tí ń wá Jèhófà.+   Gbogbo wọn ti yí padà, gbogbo wọn pátá jẹ́ ẹni ìbàjẹ́;+Kò sí ẹni tí ń ṣe rere,+Kò tilẹ̀ sí ẹyọ kan.   Kò ha sí ìkankan lára àwọn aṣenilọ́ṣẹ́ tí ó ní ìmọ̀ ni,+Tí wọ́n ń jẹ àwọn ènìyàn mi bí ẹní ń jẹ oúnjẹ?+Wọn kò tilẹ̀ ké pe Jèhófà.+   Ibẹ̀ ni wọ́n ti kún fún ìbẹ̀rùbojo ńláǹlà,+Níbi tí ìbẹ̀rùbojo kò sí;+Nítorí ó dájú pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò tú egungun ẹnikẹ́ni tí ó bá dó tì ọ́ ká.+Dájúdájú, ìwọ yóò kó ìtìjú bá wọn, nítorí pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ti kọ̀ wọ́n.+   Ìgbàlà títóbi lọ́lá fún Ísírẹ́lì ì bá jẹ́ jáde wá láti Síónì!+Nígbà tí Jèhófà bá kó àwọn òǹdè lára àwọn ènìyàn rẹ̀ jọ padà,+Kí Jékọ́bù kún fún ìdùnnú, kí Ísírẹ́lì yọ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé