Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 52:1-9

Sí olùdarí. Másíkílì. Ti Dáfídì, nígbà tí Dóẹ́gì ọmọ Édómù wá, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Sọ́ọ̀lù, tí ó sì wí fún un pé Dáfídì wá sí ilé Áhímélékì.+ 52  Èé ṣe tí ìwọ ń fi ohun búburú ṣògo, ìwọ alágbára ńlá?+ Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ti Ọlọ́run wà láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.+   Àgbákò ni ahọ́n rẹ ń pète-pèrò, a pọ́n ọn bí abẹ fẹ́lẹ́,+ Ó ń ṣiṣẹ́ ẹ̀tàn.+   Ìwọ nífẹ̀ẹ́ ohun búburú ju ohun rere,+ Ìwọ nífẹ̀ẹ́ èké ju sísọ òdodo.+ Sélà.   Ìwọ nífẹ̀ẹ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí ń jẹni run,+ Ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn.+   Ọlọ́run tìkára rẹ̀ yóò sì bì ọ́ wó títí láé;+ Òun yóò là ọ́ mọ́lẹ̀, yóò sì ya ọ́ kúrò nínú àgọ́ rẹ,+ Dájúdájú, òun yóò fà ọ́ tu kúrò ní ilẹ̀ àwọn alààyè.+ Sélà.   Àwọn olódodo yóò sì rí i, àyà yóò sì fò wọ́n,+ Wọn yóò sì máa fi í rẹ́rìn-ín.+   Abarapá ọkùnrin tí kò fi Ọlọ́run ṣe odi agbára rẹ̀ rèé,+ Ṣùgbọ́n tí ó gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀pọ̀ yanturu ọrọ̀ rẹ̀,+ Tí ó ń fi àgbákò láti ọwọ́ rẹ̀ ṣe ibi ààbò.+   Ṣùgbọ́n èmi yóò rí bí igi ólífì gbígbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀+ nínú ilé Ọlọ́run; Mo gbẹ́kẹ̀ lé inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ti Ọlọ́run fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.+   Ṣe ni èmi yóò máa gbé ọ lárugẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin, nítorí pé ìwọ ti gbé ìgbésẹ̀;+ Èmi yóò sì ní ìrètí nínú orúkọ rẹ, nítorí tí ó dára, ní iwájú àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé