Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 51:1-19

Sí olùdarí. Orin atunilára ti Dáfídì. Nígbà tí Nátánì wòlíì wọlé tọ̀ ọ́ wá lẹ́yìn tí ó ti ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú Bátí-ṣébà.+ 51  Fi ojú rere hàn sí mi, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́.+ Nu àwọn ìrélànàkọjá mi kúrò gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ yanturu àánú rẹ.+   Wẹ̀ mí mọ́ tónítóní kúrò nínú ìṣìnà mi,+ Kí o sì wẹ̀ mí mọ́ àní kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi.+   Nítorí èmi fúnra mi mọ àwọn ìrélànàkọjá mi,+ Ẹ̀ṣẹ̀ mi sì ń bẹ ní iwájú mi nígbà gbogbo.+   Ìwọ, ìwọ nìkan ṣoṣo, ni mo dẹ́ṣẹ̀ sí,+ Mo sì ti ṣe ohun tí ó burú ní ojú rẹ,+ Kí ìwọ lè jẹ́ olódodo nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀,+ Kí o lè mọ́ kúrò nínú ẹ̀bi nígbà tí o bá ń ṣe ìdájọ́.+   Wò ó! Pẹ̀lú ìṣìnà ni a bí mi nínú ìrora ìbímọ,+ Nínú ẹ̀ṣẹ̀ sì ni ìyá mi lóyún mi.+   Wò ó! Ìwọ ní inú dídùn sí òtítọ́ ní ìhà inú;+ Kí o sì jẹ́ kí n mọ kìkìdá ọgbọ́n níhà ìkọ̀kọ̀ inú ara lọ́hùn-ún.+   Kí o fi hísópù wẹ̀ mí mọ́ gaara kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀, kí n lè mọ́;+ Kí o wẹ̀ mí, kí n lè di funfun, àní ju ìrì dídì.+   Kí o mú kí n gbọ́ ayọ̀ ńláǹlà àti ayọ̀ yíyọ̀,+ Kí egungun tí ìwọ ti fọ́ lè kún fún ìdùnnú.+   Pa ojú rẹ mọ́ kúrò lára àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi,+ Kí o sì nu gbogbo ìṣìnà mi pàápàá kúrò.+ 10  Àní kí o dá ọkàn-àyà mímọ́ gaara sínú mi, Ọlọ́run,+ Kí o sì fi ẹ̀mí tuntun sínú mi, ọ̀kan tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin.+ 11  Má ṣe gbé mi sọnù kúrò níwájú rẹ;+ Ẹ̀mí mímọ́ rẹ ni kí o má sì gbà kúrò lára mi.+ 12  Mú ayọ̀ ńláǹlà ìgbàlà rẹ padà bọ̀ sípò fún mi,+ Kí o sì fi ẹ̀mí ìmúratán+ pàápàá tì mí lẹ́yìn. 13  Dájúdájú, èmi yóò kọ́ àwọn olùrélànàkọjá ní àwọn ọ̀nà rẹ,+ Kí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá lè yí padà tààràtà sọ́dọ̀ rẹ.+ 14  Dá mi nídè lọ́wọ́ ìjẹ̀bi ẹ̀jẹ̀,+ ìwọ Ọlọ́run tí í ṣe Ọlọ́run ìgbàlà mi,+ Kí ahọ́n mi lè máa fi ìdùnnú sọ nípa òdodo rẹ.+ 15  Jèhófà, kí o ṣí ètè tèmi yìí,+ Kí ẹnu mi lè máa sọ ìyìn rẹ jáde.+ 16  Nítorí ìwọ kò ní inú dídùn sí ẹbọ—bí bẹ́ẹ̀ bá ni, èmi ì bá rú u;+ Ìwọ kò ní ìdùnnú sí odindi ọrẹ ẹbọ sísun.+ 17  Àwọn ẹbọ sí Ọlọ́run ni ẹ̀mí tí ó ní ìròbìnújẹ́;+ Ọkàn-àyà tí ó ní ìròbìnújẹ́ tí ó sì wó palẹ̀ ni ìwọ, Ọlọ́run, kì yóò tẹ́ńbẹ́lú.+ 18  Nínú ìfẹ́ rere rẹ, ṣe Síónì dáadáa;+ Kí o mọ ògiri Jerúsálẹ́mù.+ 19  Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò ní inú dídùn sí àwọn ẹbọ òdodo,+ Sí ẹbọ sísun àti odindi ọrẹ ẹbọ;+ Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn akọ màlúù ni a ó fi rúbọ lórí pẹpẹ rẹ gan-an.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé