Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 50:1-23

Orin atunilára ti Ásáfù.+ 50  Olú Ọ̀run,+ Ọlọ́run, Jèhófà,+ ti fúnra rẹ̀ sọ̀rọ̀,+Ó sì tẹ̀ síwájú láti pe ilẹ̀ ayé,+Láti yíyọ oòrùn títí di wíwọ̀ rẹ̀.+   Láti Síónì, tí í ṣe ìjẹ́pípé ẹwà ìfanimọ́ra,+ ni Ọlọ́run tìkára rẹ̀ ti tàn yanran jáde.+   Ọlọ́run wa yóò wá, kò sì ṣeé ṣe pé kí ó dákẹ́.+Iná ń jẹ run níwájú rẹ̀,+Ní gbogbo àyíká rẹ̀, ojú ọjọ́ ti di oníjì lọ́nà tí ó peléke.+   Ó ké pe ọ̀run lókè, ó sì ké pe ilẹ̀ ayé+Láti lè mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún sórí àwọn ènìyàn rẹ̀+ pé:   “Ẹ kó àwọn ẹni ìdúróṣinṣin mi jọ sọ́dọ̀ mi,+Àwọn tí ó dá májẹ̀mú mi lórí ẹbọ.”+   Àwọn ọ̀run sì ń sọ nípa òdodo rẹ̀,+Nítorí pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni Onídàájọ́.+ Sélà.   “Ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi, dájúdájú èmi yóò sọ̀rọ̀,+Ìwọ Ísírẹ́lì, èmi yóò sì jẹ́rìí lòdì sí ọ.+Èmi ni Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ.+   Èmi kò bá ọ wí nípa àwọn ẹbọ rẹ,+Tàbí nípa àwọn odindi ọrẹ ẹbọ sísun rẹ tí ń bẹ ní iwájú mi nígbà gbogbo.+   Dájúdájú, èmi kì yóò mú akọ màlúù kan nínú ilé rẹ,+Àti àwọn òbúkọ nínú ọgbà ẹran rẹ. 10  Nítorí pé tèmi ni gbogbo ẹran inú igbó,+Àwọn ẹranko tí ń bẹ lórí ẹgbẹ̀rún òkè ńlá.+ 11  Èmi mọ olúkúlùkù ẹ̀dá abìyẹ́lápá tí ń bẹ lórí àwọn òkè ńlá ní àmọ̀dunjú,+Ògídímèje àwọn ẹran pápá gbalasa sì ń bẹ pẹ̀lú mi.+ 12  Ká ní ebi ń pa mí ni, èmi kò ní sọ fún ọ;Nítorí pé tèmi ni ilẹ̀ eléso+ àti ẹ̀kún rẹ̀.+ 13  Èmi yóò ha jẹ ẹran àwọn akọ màlúù lílágbára,+Èmi yóò ha sì mu ẹ̀jẹ̀ àwọn òbúkọ bí?+ 14  Rú ìdúpẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ rẹ sí Ọlọ́run,+Kí o sì san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ fún Ẹni Gíga Jù Lọ;+ 15  Kí o sì pè mí ní ọjọ́ wàhálà.+Èmi yóò gbà ọ́ sílẹ̀, ìwọ yóò sì máa yìn mí lógo.”+ 16  Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò sọ fún ẹni burúkú pé:+“Ẹ̀tọ́ wo ni ìwọ ní láti máa ka àwọn ìlànà mi lẹ́sẹẹsẹ,+Tí ìwọ yóò sì máa sọ̀rọ̀ májẹ̀mú mi ní ẹnu rẹ?+ 17  Họ́wù, ìwọ—ìwọ kórìíra ìbáwí,+Ìwọ sì ń ju ọ̀rọ̀ mi sẹ́yìn rẹ.+ 18  Nígbàkigbà tí o bá rí olè, inú rẹ tilẹ̀ ń dùn sí i;+Ìpín rẹ sì ń bẹ pẹ̀lú àwọn panṣágà.+ 19  Ìwọ ti la ẹnu rẹ gbùà sí ohun búburú,+O sì so ahọ́n rẹ mọ́ ẹ̀tàn.+ 20  Ìwọ jókòó, ìwọ sì sọ̀rọ̀ lòdì sí arákùnrin tìrẹ,+Ìwọ sì gbé àléébù ọmọ ìyá rẹ sáyé.+ 21  Nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ ṣe, mo sì dákẹ́.+Ìwọ lérò pé ó dájú hán-ún pé èmi yóò dà bí tìrẹ.+Èmi yóò fi ìbáwí tọ́ ọ sọ́nà,+ dájúdájú, èmi yóò mú àwọn nǹkan tọ́ ní ìṣojú rẹ.+ 22  Ẹ jọ̀wọ́, ẹ lóye èyí, ẹ̀yin tí ẹ ti gbàgbé Ọlọ́run,+Kí n má bàa fà yín ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ láìsí olùdáǹdè kankan.+ 23  Ẹni tí ń rú ìdúpẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ rẹ̀ ni ó ń yìn mí lógo;+Àti ní ti ẹni tí ń pa ọ̀nà tí a là sílẹ̀ mọ́,Dájúdájú, èmi yóò jẹ́ kí ó rí ìgbàlà láti ọwọ́ Ọlọ́run.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé