Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 5:1-12

Sí olùdarí fún Néhílótì. Orin atunilára ti Dáfídì. 5  Fi etí sí àwọn àsọjáde mi,+ Jèhófà; Lóye ìmí ẹ̀dùn mi.   Fetí sí ìró igbe mi fún ìrànlọ́wọ́,+ Ìwọ Ọba+ mi àti Ọlọ́run mi, nítorí pé ìwọ ni mo ń gbàdúrà sí.+   Jèhófà, ní òwúrọ̀, ìwọ yóò gbọ́ ohùn mi;+ Ní òwúrọ̀, èmi yóò darí àfiyèsí mi sọ́dọ̀ rẹ, èmi yóò sì máa ṣọ́nà.+   Nítorí pé ìwọ kì í ṣe Ọlọ́run tí ń ní inú dídùn sí ìwà burúkú;+ Kò sí ẹni búburú tí ó lè bá ọ gbé fún ìgbà èyíkéyìí.+   Kò sí àwọn aṣògo tí ó lè mú ìdúró wọn ní iwájú rẹ.+ Ìwọ kórìíra gbogbo àwọn aṣenilọ́ṣẹ́;+   Ìwọ yóò pa àwọn tí ń purọ́ run.+ Ẹni ìtàjẹ̀sílẹ̀+ àti ẹni ẹ̀tàn+ ni Jèhófà ń ṣe họ́ọ̀ sí.   Ní tèmi, èmi yóò wá sínú ilé rẹ+ Nínú ọ̀pọ̀ yanturu inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́,+ Èmi yóò tẹrí ba síhà tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ nínú ẹ̀rù rẹ.+   Jèhófà, ṣamọ̀nà mi nínú òdodo rẹ+ nítorí àwọn ọ̀tá mi;+ Mú ọ̀nà rẹ tẹ́jú níwájú mi.+   Nítorí tí kò sí nǹkan kan tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé ní ẹnu wọn;+ Àgbákò gidi ni ìhà inú wọn.+ Ibi ìsìnkú tí ó ṣí sílẹ̀ ni ọ̀fun wọn;+ Ahọ́n dídùn mọ̀ràn-ìn mọran-in ni wọ́n ń lò.+ 10  Dájúdájú, Ọlọ́run yóò kà wọ́n sí ẹlẹ́bi;+ Wọn yóò ṣubú nítorí àwọn ìmọ̀ràn tiwọn.+ Nínú ògìdìgbó ìrélànàkọjá wọn, kí wọ́n di fífọ́nká.+ Nítorí pé wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ.+ 11  Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí ń sá di ọ́ yóò máa yọ̀;+ Fún àkókò tí ó lọ kánrin ni wọn yóò máa fi ìdùnnú ké jáde.+ Ìwọ yóò sì dí ọ̀nà àbáwọlé sọ́dọ̀ wọn, Àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ orúkọ rẹ yóò sì máa yọ ayọ̀ ńláǹlà nínú rẹ.+ 12  Nítorí pé ìwọ tìkára rẹ, Jèhófà, yóò bù kún olódodo;+ Ìtẹ́wọ́gbà ni ìwọ yóò fi yí wọn ká+ bí apata ńlá.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé