Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 49:1-20

Sí olùdarí. Ti àwọn ọmọ Kórà.+ Orin atunilára. 49  Ẹ gbọ́ èyí, gbogbo ènìyàn. Ẹ fi etí sí i, gbogbo ẹ̀yin olùgbé inú ètò àwọn nǹkan,+   Ẹ̀yin ọmọ ìran ènìyàn àti ẹ̀yin ọmọ ènìyàn, Ìwọ ọlọ́rọ̀ àti ìwọ òtòṣì lápapọ̀.+   Ẹnu mi yóò sọ àwọn ohun ọgbọ́n,+ Àṣàrò inú ọkàn-àyà mi yóò sì jẹ́ ti àwọn ohun òye.+   Èmi yóò dẹ etí mi sí gbólóhùn òwe;+ Háàpù ni èmi yóò fi pa àlọ́ mi.+   Èé ṣe tí èmi yóò fi máa fòyà ní àwọn ọjọ́ ibi,+ Nígbà tí àwọn ìṣìnà olùfèrúgbapò mi yí mi ká?+   Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ lé àlùmọ́ọ́nì ìgbọ́bùkátà ara wọn,+ Tí wọ́n sì ń ṣògo nípa ọ̀pọ̀ yanturu ọrọ̀ wọn,+   Kò sí ẹnì kankan nínú wọn tí ó lè tún arákùnrin kan pàápàá rà padà+ ní ọ̀nà èyíkéyìí, Tàbí kí ó fún Ọlọ́run ní ìràpadà nítorí rẹ̀;   (Iye owó ìtúnràpadà ọkàn wọn ṣe iyebíye+ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ Tí ó fi jẹ́ pé ó ti kásẹ̀ nílẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin)   Tí yóò ṣì fi wà láàyè títí láé, kí ó má sì rí kòtò.+ 10  Nítorí ó ń rí i pé àwọn ọlọ́gbọ́n pàápàá ń kú,+ Arìndìn àti ẹni tí kì í ronú jọ ń ṣègbé,+ Wọn yóò sì fi àlùmọ́ọ́nì ìgbọ́bùkátà wọn sílẹ̀ fún àwọn mìíràn.+ 11  Ìdàníyàn wọn àtinúwá ni pé kí ilé wọn lè wà fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ Kí àgọ́ wọn wà láti ìran dé ìran.+ Wọ́n fi orúkọ wọn pe àwọn ilẹ̀ ìní wọn.+ 12  Síbẹ̀síbẹ̀, ará ayé, bí ó tilẹ̀ wà nínú ọlá, kò lè máa wà nìṣó;+ Ní tòótọ́, ó ṣée fi wé àwọn ẹranko tí a ti pa run.+ 13  Èyí ni ọ̀nà àwọn tí ó ya dìndìnrìn,+ Àti ti àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn wọn, tí ó ní ìdùnnú sí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn. Sélà. 14  Bí àgùntàn, a ti yàn wọ́n kalẹ̀ fún Ṣìọ́ọ̀lù;+ Ikú ni yóò ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn;+ Àwọn adúróṣánṣán yóò sì jọba lé wọn lórí ní òwúrọ̀,+ Ìrísí wọn yóò sì ṣá;+ Ṣìọ́ọ̀lù, dípò ibùjókòó gíga fíofío, ní ń bẹ fún olúkúlùkù wọn.+ 15  Àmọ́ ṣá o, Ọlọ́run tìkára rẹ̀ yóò tún ọkàn mi rà padà kúrò ní ọwọ́ Ṣìọ́ọ̀lù,+ Nítorí òun yóò gbà mí. Sélà. 16  Má fòyà nítorí pé ẹnì kan ń jèrè ọrọ̀,+ Nítorí pé ògo ilé rẹ̀ ń pọ̀ sí i,+ 17  Nítorí pé nígbà ikú rẹ̀, kò lè mú nǹkan kan dání rárá;+ Ògo rẹ̀ kì yóò bá òun alára sọ̀ kalẹ̀.+ 18  Nítorí pé ní ìgbà ayé rẹ̀, ó ń súre fún ọkàn ara rẹ̀;+ (Àwọn ènìyàn yóò sì máa gbé ọ lárugẹ nítorí tí ìwọ ń ṣe rere fún ara rẹ)+ 19  Nígbẹ̀yìn, kìkì ọ̀dọ̀ ìran àwọn baba ńlá rẹ̀ ni ọkàn rẹ̀ dé.+ Wọn kì yóò rí ìmọ́lẹ̀ mọ́ láé.+ 20  Ará ayé tí kò lóye, bí ó tilẹ̀ wà nínú ọlá,+ Ní tòótọ́, ṣeé fi wé àwọn ẹranko tí a ti pa run.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé