Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 48:1-14

Orin. Orin atunilára ti àwọn ọmọ Kórà.+ 48  Jèhófà tóbi, ó sì yẹ fún ìyìn púpọ̀púpọ̀+ Ní ìlú ńlá Ọlọ́run wa,+ ní òkè ńlá mímọ́ rẹ̀.+   Rírẹwà lọ́nà gíga fíofío, ayọ̀ ńláǹlà gbogbo ilẹ̀ ayé,+ Ni Òkè Ńlá Síónì ní ìhà jíjìnnàréré ní àríwá,+ Ìlú Ọba Títóbi Lọ́lá.+   Nínú àwọn ilé gogoro ibùgbé ibẹ̀, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ti di ẹni tí a mọ̀ sí ibi gíga ààbò.+   Nítorí, wò ó! àwọn ọba alára ti pàdé pọ̀ nípasẹ̀ àdéhùn,+ Wọ́n ti jùmọ̀ kọjá lọ.+   Àwọn fúnra wọn rí i; kàyéfì sì ṣe wọ́n. Ìyọlẹ́nu dé bá wọn, a mú wọn sá lọ nínú ìbẹ̀rù jìnnìjìnnì.+   Àní ìwárìrì gbá wọn mú níbẹ̀,+ Ìroragógó ìbímọ bí ti obìnrin tí ó fẹ́ bímọ.+   Ìwọ fi ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn fọ́ àwọn ọkọ̀ òkun Táṣíṣì bàjẹ́.+   Gẹ́gẹ́ bí àwa ti gbọ́ ọ, bẹ́ẹ̀ ni àwa ti rí i+ Ní ìlú ńlá Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ní ìlú ńlá Ọlọ́run wa.+ Ọlọ́run tìkára rẹ̀ yóò fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ Sélà.   Ọlọ́run, àwa ti fẹ̀sọ̀ ronú lórí inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́,+ Ní àárín tẹ́ńpìlì rẹ.+ 10  Bí orúkọ rẹ ti rí,+ Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ìyìn rẹ rí Títí dé àwọn ojú ààlà ilẹ̀ ayé. Ọwọ́ ọ̀tún rẹ kún fún òdodo.+ 11  Kí Òkè Ńlá Síónì+ máa yọ̀, Kí àwọn àrọko Júdà kún fún ìdùnnú,+ ní tìtorí àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ.+ 12  Ẹ rìn yí Síónì ká, kí ẹ sì lọ káàkiri nínú rẹ̀,+ Ẹ ka àwọn ilé gogoro rẹ̀.+ 13  Ẹ jẹ́ kí ọkàn-àyà yín ṣàníyàn nípa ohun àfiṣe-odi rẹ̀.+ Ẹ bẹ àwọn ilé gogoro ibùgbé rẹ̀ wò, Kí ẹ lè ròyìn rẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ fún ìran ẹ̀yìn ọ̀la.+ 14  Nítorí pé Ọlọ́run yìí, Ọlọ́run wa ni fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.+ Òun fúnra rẹ̀ yóò máa ṣamọ̀nà wa títí a ó fi kú.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé