Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 46:1-11

Sí olùdarí. Ti àwọn ọmọ Kórà+ lórí Àwọn Omidan. Orin. 46  Ọlọ́run jẹ́ ibi ìsádi àti okun fún wa,+ Ìrànlọ́wọ́ tí a lè rí tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn nígbà wàhálà.+   Ìdí nìyẹn tí àwa kì yóò bẹ̀rù, bí ilẹ̀ ayé tilẹ̀ yí padà,+ Bí àwọn òkè ńláńlá tilẹ̀ ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n wọ àárín alagbalúgbú òkun;+   Bí omi rẹ̀ tilẹ̀ di aláriwo líle, tí ó ń yọ ìfófòó sókè,+ Bí àwọn òkè ńláńlá tilẹ̀ mì jìgìjìgì nítorí ìrọ́kẹ̀kẹ̀ rẹ̀.+ Sélà.   Odò kan wà tí ṣíṣàn rẹ̀ ń mú kí ìlú ńlá Ọlọ́run máa yọ̀,+ Atóbilọ́lá àgọ́ ìjọsìn mímọ́ jù lọ ti Ẹni Gíga Jù Lọ.+   Ọlọ́run ń bẹ ní àárín ìlú ńlá náà;+ a kì yóò mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.+ Ọlọ́run yóò ràn án lọ́wọ́ nígbà tí òwúrọ̀ bá fara hàn.+   Àwọn orílẹ̀-èdè di aláriwo líle,+ àwọn ìjọba ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n; Ó fọ ohùn rẹ̀, ilẹ̀ ayé bẹ̀rẹ̀ sí yọ́.+   Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wà pẹ̀lú wa;+ Ọlọ́run Jékọ́bù jẹ́ ibi gíga ààbò fún wa.+ Sélà.   Ẹ wá wo àwọn ìgbòkègbodò Jèhófà,+ Bí ó ti gbé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayanilẹ́nu kalẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.+   Ó mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.+ Ó ṣẹ́ ọrun sí wẹ́wẹ́, ó sì ké ọ̀kọ̀ sí wẹ́wẹ́;+ Ó sun àwọn kẹ̀kẹ́ nínú iná.+ 10  “Ẹ juwọ́ sílẹ̀, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ni Ọlọ́run.+ Dájúdájú, a óò gbé mi ga láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+ A óò gbé mi ga ní ilẹ̀ ayé.”+ 11  Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wà pẹ̀lú wa;+ Ọlọ́run Jékọ́bù jẹ́ ibi gíga ààbò fún wa.+ Sélà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé