Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 44:1-26

Sí olùdarí. Ti àwọn ọmọ Kórà.+ Másíkílì. 44  Ọlọ́run, etí wa ni a fi gbọ́,Àwọn baba ńlá wa alára ti ròyìn fún wa lẹ́sẹẹsẹ+Ìgbòkègbodò rẹ ní ọjọ́ wọn,+Ní àwọn ọjọ́ ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn.+   Ìwọ fúnra rẹ ni o fi ọwọ́ rẹ lé àwọn orílẹ̀-èdè pàápàá lọ,+O sì tẹ̀ síwájú láti gbìn wọ́n sí ipò wọn.+Ìwọ fọ́ àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè, o sì rán wọn lọ.+   Nítorí pé kì í ṣe idà tiwọn ni wọ́n fi gba ilẹ̀ náà,+Kì í sì í ṣe apá tiwọn ni ó mú ìgbàlà wá fún wọn.+Nítorí pé ọwọ́ ọ̀tún rẹ àti apá+ rẹ àti ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ ni,Nítorí pé ìwọ ní ìdùnnú sí wọn.+   Ìwọ tìkára rẹ ni Ọba mi, Ọlọ́run.+Pàṣẹ ìgbàlà títóbi lọ́lá fún Jékọ́bù.+   Nípasẹ̀ rẹ ni àwa yóò taari àwọn elénìní wa;+Ní orúkọ rẹ ni àwa yóò tẹ àwọn tí ó dìde sí wa mọ́lẹ̀.+   Nítorí pé kì í ṣe ọrun mi ni mo ń gbẹ́kẹ̀ lé+Kì í sì í ṣe idà mi ni ó ń gbà mí là.+   Nítorí pé ìwọ ni ó gbà wá là lọ́wọ́ àwọn elénìní wa,+Ìwọ sì kó ìtìjú bá àwọn tí ó kórìíra wa lọ́nà gbígbóná janjan.+   Ọlọ́run ni a óò máa mú ìyìn wá fún láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀,+Orúkọ rẹ sì ni a óò máa gbé lárugẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ Sélà.   Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ìwọ ti ta wá nù, o sì ń tẹ́ wa lógo,+Ìwọ kò sì bá àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa jáde lọ.+ 10  Ìwọ ń mú kí a yí padà níwájú elénìní,+Àní àwọn tí ó kórìíra wa lọ́nà gbígbóná janjan ti kó ìkógun fún ara wọn.+ 11  O jọ̀wọ́ wa lọ́wọ́ bí àgùntàn, bí nǹkan jíjẹ,+Ìwọ sì ti tú wa ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè.+ 12  Ìwọ ta àwọn ènìyàn rẹ lọ́fẹ̀ẹ́-lófò,+Ìwọ kò sì ní ọlà láti inú iye owó wọn. 13  Ìwọ ṣe wá ní ẹni ẹ̀gàn fún àwọn aládùúgbò wa,+Ẹni ìfiṣẹ̀sín àti ìfiṣeyẹ̀yẹ́ fún àwọn tí ó wà ní gbogbo àyíká wa,+ 14  Ìwọ ṣe wá ní ẹni àfipòwe láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+Ẹni tí a ń mi orí sí láàárín àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè.+ 15  Láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ ni ìtẹ́lógo mi ń bẹ ní iwájú mi,Ìtìjú mi sì ti bò mí,+ 16  Nítorí ohùn ẹni tí ń ganni, tí ó sì ń sọ̀rọ̀ síni tèébútèébú,Nítorí ọ̀tá àti ẹni tí ń gbẹ̀san.+ 17  Gbogbo èyí ni ó ti wá sórí wa, àwa kò sì gbàgbé rẹ,+Àwa kò sì ṣèké nínú májẹ̀mú rẹ.+ 18  Ọkàn-àyà wa kò fi àìnígbàgbọ́ yí padà,+Bẹ́ẹ̀ ni ipasẹ̀ wa kò yapa kúrò ní ipa ọ̀nà rẹ.+ 19  Nítorí pé ìwọ ti tẹ̀ wá rẹ́ ní ipò àwọn akátá,+Ìwọ sì fi ibú òjìji bò wá mọ́lẹ̀.+ 20  Ká ní àwa gbàgbé orúkọ Ọlọ́run wa ni,Tàbí tí a tẹ́ àtẹ́lẹwọ́ wa sí àjèjì ọlọ́run,+ 21  Ọlọ́run tìkára rẹ̀ kì yóò ha wá èyí kàn bí?+Nítorí pé ó mọ àwọn àṣírí ọkàn-àyà.+ 22  Ṣùgbọ́n nítorí tìrẹ ni a fi pa wá láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀;A ti kà wá sí àgùntàn fún pípa.+ 23  Ru ara rẹ dìde. Èé ṣe tí o fi ń sùn, Jèhófà?+Jí. Má ṣe ta wá nù títí láé.+ 24  Èé ṣe tí o fi pa ojú rẹ gan-an mọ́?Èé ṣe tí o fi gbàgbé ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ wa níṣẹ̀ẹ́ àti níni tí a ń ni wá lára?+ 25  Nítorí ọkàn wa ti tẹ̀ ba kan ekuru;+Ikùn wa ti lẹ̀ mọ́ ilẹ̀yílẹ̀. 26  Dìde láti ṣe ìrànwọ́ fún wa+Kí o sì tún wa rà padà nítorí inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé