Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 43:1-5

43  Ṣe ìdájọ́ mi,+ Ọlọ́run, Kí o sì bá mi dá ẹjọ́ mi+ lòdì sí orílẹ̀-èdè tí kò dúró ṣinṣin. Kí o pèsè àsálà fún mi kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́tàn àti aláìṣòdodo.+   Nítorí pé ìwọ ni Ọlọ́run odi agbára mi.+ Èé ṣe tí o fi ta mí nù? Èé ṣe tí mo fi ń rìn káàkiri nínú ìbànújẹ́ nítorí ìnilára láti ọwọ́ ọ̀tá?+   Rán ìmọ́lẹ̀ rẹ àti òtítọ́ rẹ jáde.+ Kí ìwọ̀nyí máa ṣamọ̀nà mi.+ Kí wọ́n mú mi wá sí òkè ńlá mímọ́ rẹ àti sí àgọ́ ìjọsìn rẹ títóbi lọ́lá.+   Dájúdájú, èmi yóò wá síbi pẹpẹ Ọlọ́run,+ Sọ́dọ̀ Ọlọ́run, ayọ̀ yíyọ̀ mi tí ó kún fún ayọ̀ ńláǹlà.+ Èmi yóò sì fi háàpù gbé ọ lárugẹ, Ọlọ́run, ìwọ Ọlọ́run mi.+   Èé ṣe tí o fi ń bọ́hùn, ìwọ ọkàn mi,+ Èé sì ti ṣe tí o fi ń ru gùdù nínú mi? Dúró de Ọlọ́run,+ Nítorí pé síbẹ̀síbẹ̀, èmi yóò máa gbé e lárugẹ gẹ́gẹ́ bí ìgbàlà títóbi lọ́lá fún èmi alára àti gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run mi.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé