Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 42:1-11

Sí olùdarí. Másíkílì fún àwọn ọmọ Kórà.+ 42  Bí egbin tí ń yánhànhàn fún ìṣàn omi, Bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi gan-an ń yánhànhàn fún ọ, Ọlọ́run.+   Òùngbẹ Ọlọ́run,+ àní Ọlọ́run alààyè,+ ń gbẹ ọkàn mi ní tòótọ́, Ìgbà wo ni èmi yóò wá, tí èmi yóò sì fara hàn níwájú Ọlọ́run?+   Omijé mi ti di oúnjẹ mi ní ọ̀sán àti ní òru,+ Bí wọ́n ti ń sọ fún mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ pé: “Ọlọ́run rẹ dà?”+   Nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò rántí, èmi yóò sì tú ọkàn mi jáde nínú mi.+ Nítorí pé mo ti máa ń bá ọ̀pọ̀ ènìyàn kọjá lọ tẹ́lẹ̀ rí, Mo ti máa ń rọra rìn níwájú wọn lọ sí ilé Ọlọ́run tẹ́lẹ̀ rí,+ Pẹ̀lú ohùn igbe ìdùnnú àti ìdúpẹ́,+ Ti ogunlọ́gọ̀ tí ń ṣe àjọyọ̀.+   Èé ṣe tí o fi ń bọ́hùn, ìwọ ọkàn mi,+ Èé sì ti ṣe tí o fi ń ru gùdù nínú mi?+ Dúró de Ọlọ́run,+ Nítorí pé síbẹ̀síbẹ̀, èmi yóò máa gbé e lárugẹ gẹ́gẹ́ bí ìgbàlà títóbi lọ́lá fún èmi alára.+   Ìwọ Ọlọ́run mi, àní ọkàn mi ń bọ́hùn nínú mi.+ Ìdí nìyẹn tí mo fi rántí rẹ,+ Láti ilẹ̀ Jọ́dánì àti àwọn téńté Hámónì,+ Láti òkè ńlá tí kò fi bẹ́ẹ̀ ga.+   Ibú omi ń ké sí ibú omi Nípa ìró àwọn ìdàṣọ̀ọ̀rọ̀ (omi) rẹ. Gbogbo ìrugùdù omi rẹ tí ń fọ́n ká di ìfóófòó àti ìgbì rẹ+ Wọ́n ti kọjá lórí mi.+   Ní ọ̀sán, Jèhófà yóò pàṣẹ inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́,+ Àti ní òru, orin rẹ̀ yóò wà pẹ̀lú mi;+ Àdúrà yóò wà sí Ọlọ́run ìwàláàyè mi.+   Dájúdájú, èmi yóò wí fún Ọlọ́run àpáta gàǹgà mi pé:+ “Èé ṣe tí o fi gbàgbé mi?+ Èé ṣe tí mo fi ń rìn nínú ìbànújẹ́ nítorí ìnilára ọ̀tá?”+ 10  Àwọn tí ń fi ẹ̀tanú hàn sí mi ti dá ọgbẹ́ tí ń ṣekú pani sí egungun mi láti gàn mí,+ Bí wọ́n ti ń sọ fún mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ pé: “Ọlọ́run rẹ dà?”+ 11  Èé ṣe tí o fi ń bọ́hùn, ìwọ ọkàn mi,+ Èé sì ti ṣe tí o fi ń ru gùdù nínú mi?+ Dúró de Ọlọ́run,+ Nítorí pé síbẹ̀síbẹ̀, èmi yóò máa gbé e lárugẹ gẹ́gẹ́ bí ìgbàlà títóbi lọ́lá fún èmi alára àti gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run mi.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé