Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 41:1-13

Sí olùdarí. Orin atunilára ti Dáfídì. 41  Aláyọ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ń fi ìgbatẹnirò hùwà sí ẹni rírẹlẹ̀;+Ní ọjọ́ ìyọnu àjálù, Jèhófà yóò pèsè àsálà fún un.+   Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò máa ṣọ́ ọ, yóò sì pa á mọ́ láàyè.+A óò máa pè é ní aláyọ̀ ní ilẹ̀ ayé;+Ìwọ kò sì jẹ́ fi í lé ọkàn àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́.+   Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò gbé e ró lórí àga ìnàyìn ti àmódi;+Gbogbo ibùsùn rẹ̀ ni ìwọ yóò yí padà dájúdájú nígbà àìsàn rẹ̀.+   Ní tèmi, mo wí pé: “Jèhófà, fi ojú rere hàn sí mi.+Mú ọkàn mi lára dá, nítorí pé mo ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ.”+   Ní ti àwọn ọ̀tá mi, wọ́n ń sọ ohun búburú nípa mi pé:+“Nígbà wo ni yóò kú, tí orúkọ rẹ̀ yóò sì ṣègbé ní ti gidi?”   Bí ẹnì kan bá sì wá rí mi, àìṣòótọ́ ni ọkàn-àyà rẹ̀ yóò máa sọ;+Òun yóò kó ohun aṣenilọ́ṣẹ́ jọpọ̀ fún ara rẹ̀;Òun yóò jáde lọ; yóò máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lóde.+   Ní ìsopọ̀ṣọ̀kan lòdì sí mi, gbogbo àwọn tí ó kórìíra mi ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́ lẹ́nì kìíní-kejì;+Ní ìlòdìsí mi, wọ́n ń pète-pèrò ohun búburú sí mi pé:+   “Nǹkan tí kò dára fún ohunkóhun ni a dà lé e lórí;+Nísinsìnyí tí ó ti dùbúlẹ̀, kì yóò dìde mọ́.”+   Pẹ̀lúpẹ̀lù, ẹni tí ó wà ní àlàáfíà pẹ̀lú mi, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀ lé,+Ẹni tí ó ti máa ń jẹ oúnjẹ mi,+ ti gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ ga sí mi.+ 10  Ní ti ìwọ, Jèhófà, fi ojú rere hàn sí mi, kí o sì mú kí n dìde,+Kí n lè san án padà fún wọn.+ 11  Nípa èyí ni mo mọ̀ pé ìwọ ní inú dídùn sí mi,Nítorí pé ọ̀tá mi kò fi ayọ̀ ìṣẹ́gun kígbe lé mi lórí.+ 12  Ní tèmi, ìwọ ti gbèjà mi nítorí ìwà títọ́ mi,+Ìwọ yóò sì gbé mi kalẹ̀ sí iwájú rẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ 13  Ìbùkún ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì+Láti àkókò tí ó lọ kánrin, àní dé àkókò tí ó lọ kánrin.+Àmín àti Àmín.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé