Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 40:1-17

Sí olùdarí. Ti Dáfídì, orin atunilára. 40  Taratara ni mo fi ní ìrètí nínú Jèhófà,+ Nítorí náà, ó dẹ etí rẹ̀ sí mi, ó sì gbọ́ igbe mi fún ìrànlọ́wọ́.+   Ó sì tẹ̀ síwájú láti mú mi gòkè pẹ̀lú láti inú kòtò tí ń ké ramúramù,+ Láti inú ẹrẹ̀ pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀.+ Nígbà náà ni ó gbé ẹsẹ̀ mi sókè sórí àpáta gàǹgà;+ Ó fi àwọn ìṣísẹ̀ mi múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.+   Síwájú sí i, ó fi orin tuntun sí mi lẹ́nu, Ìyìn sí Ọlọ́run wa.+ Ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò rí i, wọn yóò sì bẹ̀rù,+ Wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.+   Aláyọ̀ ni abarapá ọkùnrin tí ó fi Jèhófà ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀+ Tí kò sì yíjú sí àwọn aṣàyàgbàǹgbà-peni-níjà, Tàbí sí àwọn tí ń yà sínú irọ́.+   Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ìwọ fúnra rẹ ti ṣe,+ Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, àní àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ àti ìrònú rẹ sí wa;+ Kò sí ẹnì kankan tí a lè fi ọ́ wé.+ Ká ní mo fẹ́ máa wí, kí n sì máa sọ nípa wọn ni, Wọ́n pọ̀ níye ju èyí tí mo lè máa ròyìn lẹ́sẹẹsẹ.+   Ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ ni ìwọ kò ní inú dídùn sí;+ Etí tèmi yìí ni ìwọ là sílẹ̀.+ Ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni ìwọ kò béèrè.+   Nítorí èyí, mo wí pé: “Kíyè sí i, mo ti dé,+ Nínú àkájọ ìwé ni a ti kọ ọ́ nípa mi.+   Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi, ni mo ní inú dídùn sí,+ Òfin rẹ sì ń bẹ ní ìhà inú mi.+   Mo ti sọ ìhìn rere òdodo nínú ìjọ ńlá.+ Wò ó! Èmi kò ṣèdíwọ́ fún ètè mi.+ Jèhófà, ìwọ alára mọ ìyẹn ní àmọ̀dunjú.+ 10  Èmi kò bo òdodo rẹ mọ́lẹ̀ ní ọkàn-àyà mi.+ Mo ti polongo ìṣòtítọ́ rẹ àti ìgbàlà rẹ.+ Èmi kò fi inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ àti òótọ́ rẹ pa mọ́ nínú ìjọ ńlá.”+ 11  Ìwọ alára, Jèhófà, má fa ojú àánú rẹ sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi.+ Jẹ́ kí inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ àti òótọ́ rẹ máa fi ìṣọ́ ṣọ́ mi nígbà gbogbo.+ 12  Nítorí pé àwọn ìyọnu àjálù ká mi mọ́ títí iye wọn kò fi ṣeé kà.+ Ọ̀pọ̀ ìṣìnà tèmi lé mi bá ju bí mo ti lè rí i;+ Wọ́n pọ̀ níye ju irun orí mi,+ Ọkàn-àyà mi sì fi mí sílẹ̀.+ 13  Kí ó dùn mọ́ ọ nínú, Jèhófà, láti dá mi nídè.+ Jèhófà, ṣe kánkán láti wá ṣe ìrànwọ́ fún mi.+ 14  Kí ojú tì wọ́n, kí gbogbo wọn sì tẹ́ pa pọ̀,+ Àwọn tí ń wá ọkàn mi láti gbá a lọ.+ Kí wọ́n yí padà, kí a sì tẹ́ wọn lógo, àwọn tí ó ní inú dídùn sí ìyọnu àjálù mi.+ 15  Kí wọ́n máa wò sùn-ùn pẹ̀lú kàyéfì nítorí ìtìjú wọn,+ Àwọn tí ń wí fún mi pé: “Àháà! Àháà!”+ 16  Kí wọ́n máa yọ ayọ̀ ńláǹlà, kí wọ́n sì máa yọ̀ nínú rẹ,+ Gbogbo àwọn tí ń wá ọ.+ Kí wọ́n máa wí nígbà gbogbo pé: “Kí Jèhófà di àgbégalọ́lá,”+ Àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ ìgbàlà tí ó ti ọ̀dọ̀ rẹ wá.+ 17  Ṣùgbọ́n ẹni tí a ń ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́ àti òtòṣì ni mí.+ Jèhófà tìkára rẹ̀ ń gba tèmi rò.+ Ìwọ ni ìrànwọ́ mi àti Olùpèsè àsálà fún mi.+ Ìwọ Ọlọ́run mi, má ṣe pẹ́ jù.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé