Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 39:1-13

Sí olùdarí Jédútúnì.+ Orin atunilára ti Dáfídì. 39  Mo wí pé: “Ṣe ni èmi yóò máa ṣọ́ àwọn ọ̀nà mi+ Láti má ṣe fi ahọ́n mi dẹ́ṣẹ̀.+ Ṣe ni èmi yóò fi ìdínu tí ó rí bí ẹ̀ṣọ́ dí ẹnu mi,+ Níwọ̀n ìgbà tí ẹni burúkú bá ti wà ní iwájú mi.”+   Mo fi ìdákẹ́jẹ́ẹ́ di aláìlèsọ̀rọ̀;+ Mo dákẹ́ jẹ́ẹ́ sí ohun rere,+ Wíwà tí mo wà nínú ìrora ni a sì ta nù lẹ́gbẹ́.   Ọkàn-àyà mi gbóná nínú mi;+ Nígbà ìmí ẹ̀dùn mi, iná ń jó. Mo fi ahọ́n mi sọ̀rọ̀ pé:   “Jèhófà, jẹ́ kí n mọ òpin mi,+ Àti ìwọ̀n ọjọ́ mi—ohun tí ó jẹ́,+ Kí n lè mọ bí mo ti jẹ́ aláìwàpẹ́ tó.+   Wò ó! Ìwọ ti ṣe ọjọ́ mi ní kìkì ìwọ̀nba díẹ̀;+ Gbogbo ọjọ́ ayé mi sì dà bí èyí tí kò tó nǹkan ní iwájú rẹ.+ Dájúdájú, olúkúlùkù ará ayé, bí ó tilẹ̀ dúró gbọn-in gbọn-in, jẹ́ èémí àmíjáde lásán-làsàn.+ Sélà.   Dájúdájú, ní àwòrán ni ènìyàn ń rìn káàkiri.+ Dájúdájú, lásán ni wọ́n jẹ́ aláriwo líle.+ Ènìyàn ń to nǹkan jọ pelemọ, kò sì mọ ẹni tí yóò kó wọn.+   Wàyí o, kí ni mo ní ìrètí fún, Jèhófà? Ìfojúsọ́nà mi ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ.+   Dá mi nídè nínú gbogbo ìrélànàkọjá mi.+ Má ṣe gbé mi kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni ẹ̀gàn fún òpònú.+   Mo ń bá a nìṣó ní jíjẹ́ aláìlèsọ̀rọ̀;+ èmi kò lè la ẹnu mi,+ Nítorí tí ìwọ fúnra rẹ gbé ìgbésẹ̀.+ 10  Mú ìyọnu rẹ kúrò lára mi.+ Èmi ti wá sí òpin nítorí ìbánijà ọwọ́ rẹ.+ 11  Nípasẹ̀ àwọn ìbáwí àfitọ́nisọ́nà lórí ìṣìnà ni ìwọ ti tọ́ ènìyàn sọ́nà,+ Ìwọ sì jẹ àwọn ohun tí ó ní ìfẹ́-ọkàn sí run gẹ́gẹ́ bí òólá+ ti ń ṣe. Dájúdájú, olúkúlùkù ará ayé jẹ́ èémí àmíjáde.+ Sélà. 12  Gbọ́ àdúrà mi, Jèhófà, Sì fi etí sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́.+ Má ṣe dákẹ́ sí omijé mi.+ Nítorí pé àtìpó lásán ni mo jẹ́ lọ́dọ̀ rẹ,+ Olùtẹ̀dó bákan náà bí gbogbo baba ńlá mi.+ 13  Yíjú kúrò lọ́dọ̀ mi, kí n lè túra ká+ Kí èmi tó lọ láìsí mọ́.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé