Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 38:1-22

Orin atunilára ti Dáfídì, láti mú wá sí ìrántí. 38  Jèhófà, má ṣe bá mi wí nínú ìkannú rẹ,+ Má sì tọ́ mi sọ́nà nínú ìhónú rẹ.+   Nítorí pé àwọn ọfà rẹ ti wọnú mi ṣinṣin,+ Ọwọ́ rẹ sì ti sọ̀ kalẹ̀ sórí mi.+   Kò sí ibì kankan tí ó dá ṣáṣá nínú ẹran ara mi nítorí ìdálẹ́bi tí ó ti ọ̀dọ̀ rẹ wá.+ Kò sí àlàáfíà kankan nínú egungun mi ní tìtorí ẹ̀ṣẹ̀ mi.+   Nítorí pé àwọn ìṣìnà mi ti gba orí mi kọjá;+ Bí ẹrù wíwúwo, wọ́n wúwo jù fún mi.+   Àwọn ọgbẹ́ mi ti ṣíyàn-án, wọ́n ti gbinnikún, Nítorí ìwà òmùgọ̀ mi.+   Mo ti di aláìbalẹ̀-ọkàn, mo ti tẹrí ba mọ́lẹ̀ ní ìwọ̀n tí ó dé góńgó;+ Láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ ni mo ń rìn káàkiri nínú ìbànújẹ́.+   Nítorí pé abẹ́nú mi gan-an ti kún fún ìjóná, Kò sì sí ibì kankan tí ó dá ṣáṣá nínú ẹran ara mi.+   Ara mi ti kú tipiri, mo sì ti di ẹni ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ní ìwọ̀n tí ó dé góńgó; Mo ti ké ramúramù nítorí ìkérora ọkàn-àyà mi.+   Jèhófà, iwájú rẹ ni gbogbo ìfẹ́-ọkàn mi wà, Ìmí ẹ̀dùn mi kò sì pa mọ́ fún ọ.+ 10  Ọkàn-àyà mi lù kì-kì-kì, agbára mi ti fi mí sílẹ̀, Pẹ̀lúpẹ̀lù, ìmọ́lẹ̀ ojú mi kò sí lọ́dọ̀ mi.+ 11  Ní ti àwọn olùfẹ́ mi àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ mi, wọ́n dúró jìnnà sí ìyọnu mi,+ Àní àwọn ojúlùmọ̀ mi tímọ́tímọ́ sì dúró sí òkèèrè.+ 12  Ṣùgbọ́n àwọn tí ń wá ọkàn mi dẹ pańpẹ́ sílẹ̀,+ Àwọn tí ó sì ń ṣiṣẹ́ ìyọnu àjálù sí mi ti sọ̀rọ̀ nípa àgbákò,+ Ẹ̀tàn sì ni wọ́n ń sọ ṣáá lábẹ́lẹ̀ láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.+ 13  Ní tèmi, bí adití, n kò ní fetí sílẹ̀;+ Àti bí ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀, n kò ní la ẹnu mi.+ 14  Mo sì wá dà bí ẹni tí kò gbọ́ràn, Kò sì sí ìjiyàn àfidáhùnpadà ní ẹnu mi. 15  Nítorí pé ìwọ, Jèhófà, ni mo dúró dè;+ Ìwọ fúnra rẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí dá mi lóhùn, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi.+ 16  Nítorí mo wí pé: “Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn yóò yọ̀ mí;+ Nígbà tí ẹsẹ̀ mi bá rìn tàgétàgé,+ dájúdájú, wọn yóò máa gbé àgbéré ńláǹlà sí mi.”+ 17  Nítorí mo ti múra láti ta gẹ̀ẹ́gẹ̀ẹ́,+ Ìrora mi sì ń bẹ ní iwájú mi nígbà gbogbo.+ 18  Nítorí tí mo bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ nípa ìṣìnà mi;+ Mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣàníyàn lórí ẹ̀ṣẹ̀ mi.+ 19  Àwọn ọ̀tá mi tí ń bẹ láàyè ti di alágbára ńlá,+ Àwọn tí ó sì kórìíra mi láìsí ìdí ti di púpọ̀.+ 20  Wọ́n sì ń fi búburú san rere fún mi;+ Wọ́n ń takò mí ṣáá ní ìdápadà fún lílépa tí mo ń lépa ohun rere.+ 21  Má fi mí sílẹ̀, Jèhófà. Ìwọ Ọlọ́run mi, má jìnnà réré sí mi.+ 22  Ṣe kánkán láti wá ṣe ìrànwọ́ fún mi,+ Ìwọ Jèhófà ìgbàlà mi.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé