Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 37:1-40

Ti Dáfídì. א [Áléfì] 37  Má ṣe gbaná jẹ nítorí àwọn aṣebi.+ Má ṣe ìlara àwọn tí ń ṣe àìṣòdodo.+   Nítorí pé bí koríko ni wọn yóò rọ pẹ̀lú ìyára kánkán,+ Àti bí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ koríko tútù ni wọn yóò rẹ̀ dànù.+ ב [Bétì]   Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí o sì máa ṣe rere;+ Máa gbé ilẹ̀ ayé, kí o sì máa fi ìṣòtítọ́ báni lò.+   Pẹ̀lúpẹ̀lù, máa ní inú dídùn kíkọyọyọ nínú Jèhófà,+ Òun yóò sì fún ọ ní àwọn ìbéèrè tí ó ti inú ọkàn-àyà rẹ wá.+ ג [Gímélì]   Yí ọ̀nà rẹ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà,+ Kí o sì gbójú lé e,+ òun yóò sì gbé ìgbésẹ̀.+   Dájúdájú, òun yóò sì mú òdodo rẹ jáde wá bí ìmọ́lẹ̀ pàápàá,+ Àti ìdájọ́ òdodo rẹ bí ọjọ́kanrí.+ ד [Dálétì]   Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Jèhófà+ Kí o sì fi ìyánhànhàn dúró dè é.+ Má ṣe gbaná jẹ mọ́ ẹnikẹ́ni tí ń mú kí ọ̀nà rẹ̀ kẹ́sẹ járí,+ Sí ènìyàn tí ń mú èrò-ọkàn rẹ̀ ṣẹ.+ ה [Híì]   Jáwọ́ nínú ìbínú, kí o sì fi ìhónú sílẹ̀;+ Má ṣe gbaná jẹ kìkì láti ṣe ibi.+   Nítorí pé àwọn aṣebi ni a óò ké kúrò,+ Ṣùgbọ́n àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà ni yóò ni ilẹ̀ ayé.+ ו [Wọ́ọ̀] 10  Àti pé ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́;+ Dájúdájú, ìwọ yóò sì fiyè sí ipò rẹ̀, òun kì yóò sì sí.+ 11  Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé,+ Ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.+ ז [Sáyínì] 12  Ẹni burúkú ń dìmọ̀ lù sí olódodo,+ Ó sì ń wa eyín pọ̀ sí i.+ 13  Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò fi í rẹ́rìn-ín,+ Nítorí tí ó rí i dájú pé ọjọ́ rẹ̀ yóò dé.+ ח [Kétì] 14  Àwọn ẹni burúkú ti fa idà pàápàá yọ, wọ́n sì ti fa ọrun wọn,+ Láti mú kí ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ àti òtòṣì ṣubú,+ Láti pa àwọn adúróṣánṣán ní ọ̀nà wọn.+ 15  Idà tiwọn fúnra wọn yóò wọnú ọkàn-àyà wọn,+ A ó sì ṣẹ́ ọrun wọn.+ ט [Tétì] 16  Díẹ̀ ti olódodo sàn ju+ Ọ̀pọ̀ yanturu ti ọ̀pọ̀ àwọn ẹni burúkú.+ 17  Nítorí apá àwọn ẹni burúkú pàápàá ni a óò ṣẹ́,+ Ṣùgbọ́n Jèhófà yóò máa ti àwọn olódodo lẹ́yìn.+ י [Yódì] 18  Jèhófà mọ iye ọjọ́ àwọn aláìní-àléébù,+ Ogún tiwọn yóò sì máa wà nìṣó, àní fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ 19  Ojú kì yóò tì wọ́n ní àkókò ìyọnu àjálù,+ Wọn yóò sì yó ní àwọn ọjọ́ ìyàn.+ כ [Káfì] 20  Nítorí pé àwọn ẹni burúkú alára yóò ṣègbé,+ Àwọn ọ̀tá Jèhófà yóò sì dà bí ṣíṣeyebíye tí àwọn pápá ìjẹko ṣeyebíye; Ṣe ni wọn yóò wá sí òpin wọn.+ Nínú èéfín ni wọn yóò wá sí òpin wọn.+ ל [Lámédì] 21  Ẹni burúkú ń yá nǹkan, kì í sì í san án padà,+ Ṣùgbọ́n olódodo ń fi ojú rere hàn, ó sì ń fúnni ní ẹ̀bùn.+ 22  Nítorí àwọn ẹni tí òun ń bù kún ni àwọn tí yóò ni ilẹ̀ ayé,+ Ṣùgbọ́n àwọn ẹni tí òun pe ibi wá sórí wọn ni a óò ké kúrò.+ מ [Mémì] 23  Nípasẹ̀ Jèhófà ni a pèsè àwọn ìṣísẹ̀ abarapá ọkùnrin sílẹ̀,+ Ọ̀nà rẹ̀ sì ni Òun ní inú dídùn sí.+ 24  Bí ó tilẹ̀ ṣubú, a kì yóò fi í sọ̀kò sísàlẹ̀,+ Nítorí pé Jèhófà ń ti ọwọ́ rẹ̀ lẹ́yìn.+ נ [Núnì] 25  Èmi ti jẹ́ ọ̀dọ́ rí, mo sì ti darúgbó,+ Síbẹ̀síbẹ̀, èmi kò tíì rí i kí a fi olódodo sílẹ̀ pátápátá,+ Tàbí kí ọmọ rẹ̀ máa wá oúnjẹ kiri.+ 26  Láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ ni ó ń fi ojú rere hàn, tí ó sì ń wínni,+ Nítorí náà, àwọn ọmọ rẹ̀ wà ní ìlà fún ìbùkún.+ ס [Sámékì] 27  Yí padà kúrò nínú ohun búburú, kí o sì máa ṣe rere,+ Kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ máa wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ 28  Nítorí pé olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà,+ Òun kì yóò sì fi àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀.+ ע [Áyínì]Fún àkókò tí ó lọ kánrin ni a óò máa ṣọ́ wọn dájúdájú;+ Ṣùgbọ́n ní ti ọmọ àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò ní tòótọ́.+ 29  Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé,+ Wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.+ פ [Péè] 30  Ẹnu olódodo ní ń sọ ọgbọ́n jáde ní ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́,+ Tirẹ̀ sì ni ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tí ó bá ìdájọ́ òdodo mu.+ 31  Òfin Ọlọ́run rẹ̀ ń bẹ ní ọkàn-àyà rẹ̀;+ Àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ kì yóò gbò yèpéyèpé.+ צ [Sádì] 32  Ẹni burúkú ń ṣọ́ olódodo,+ Ó sì ń wá ọ̀nà láti fi ikú pa á.+ 33  Ní ti Jèhófà, kì yóò fi í sílẹ̀ sí ọwọ́ ẹni yẹn,+ Òun kì yóò sì pè é ní ẹni burúkú nígbà tí a bá ń ṣèdájọ́ rẹ̀.+ ק [Kófì] 34  Ní ìrètí nínú Jèhófà, kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́,+ Òun yóò sì gbé ọ ga láti gba ilẹ̀ ayé.+ Nígbà tí a bá ké àwọn ẹni burúkú kúrò, ìwọ yóò rí i.+ ר [Réṣì] 35  Mo ti rí ẹni burúkú tí í ṣe afìkà-gboni-mọ́lẹ̀,+ Tí ó sì ń tẹ́ rẹrẹ bí igi tí ó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ ní ilẹ̀ ìbílẹ̀.+ 36  Síbẹ̀síbẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí kọjá lọ, kò sì sí níbẹ̀ mọ́;+ Mo sì ń wá a kiri, a kò sì rí i.+ ש [Ṣínì] 37  Máa ṣọ́ aláìlẹ́bi, kí o sì máa wo adúróṣánṣán,+ Nítorí pé ọjọ́ ọ̀la ẹni yẹn yóò kún fún àlàáfíà.+ 38  Ṣùgbọ́n ó dájú pé a ó pa àwọn olùrélànàkọjá rẹ́ ráúráú lápapọ̀;+ Ọjọ́ ọ̀la àwọn ènìyàn burúkú ni a óò ké kúrò ní tòótọ́.+ ת [Tọ́ọ̀] 39  Ọ̀dọ̀ Jèhófà sì ni ìgbàlà àwọn olódodo ti wá;+ Òun ni odi agbára wọn ní àkókò wàhálà.+ 40  Jèhófà yóò sì ràn wọ́n lọ́wọ́, yóò sì pèsè àsálà fún wọn.+ Òun yóò pèsè àsálà fún wọn kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn burúkú, yóò sì gbà wọ́n là,+ Nítorí pé wọ́n sá di í.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé