Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 36:1-12

Sí olùdarí. Ti Dáfídì ìránṣẹ́ Jèhófà. 36  Àsọjáde ti ìrélànàkọjá sí ẹni burúkú ń bẹ nínú ọkàn-àyà rẹ̀;+Kò sí ìbẹ̀rùbojo fún Ọlọ́run ní iwájú rẹ̀.+   Nítorí pé ó ti gbé ìgbésẹ̀ fún ara rẹ̀ lọ́nà tí ó ṣe féfé jù ní ojú ara rẹ̀+Tí yóò fi rí ìṣìnà ara rẹ̀, kí ó bàa lè kórìíra rẹ̀.+   Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ jẹ́ ọṣẹ́ àti ẹ̀tàn;+Ó ti ṣíwọ́ láti ní ìjìnlẹ̀ òye fún ṣíṣe rere.+   Ọṣẹ́ ni ó ń pète-pèrò ṣáá lórí ibùsùn rẹ̀.+Ó dúró sí ọ̀nà tí kò dára,+Kì í kọ ohun búburú.+   Jèhófà, inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ń bẹ ní ọ̀run;+Ìṣòtítọ́ rẹ ga títí dé àwọsánmà.+   Òdodo rẹ dà bí àwọn òkè ńlá Ọlọ́run;+Ìpinnu ìdájọ́ rẹ jẹ́ alagbalúgbú ibú omi,+Ènìyàn àti ẹranko ni ìwọ gbà là, Jèhófà.+   Inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ mà ṣe iyebíye o, Ọlọ́run!+Abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ sì ni àwọn ọmọ ènìyàn tìkára wọn sá di.+   Wọ́n ń mu ọ̀rá ilé rẹ ní àmuyó;+Ìwọ sì ń mú kí wọ́n mu nínú ìtúpùúpùú adùn rẹ.+   Nítorí pé ọ̀dọ̀ rẹ ni orísun ìyè wà;+Nípasẹ̀ ìmọ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ rẹ ni àwa fi lè rí ìmọ́lẹ̀.+ 10  Máa bá inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ nìṣó fún àwọn tí ó mọ̀ ọ́,+Àti òdodo rẹ fún àwọn adúróṣánṣán ní ọkàn-àyà.+ 11  Kí ẹsẹ̀ ìrera má ṣe wá lòdì sí mi;+Ní ti ọwọ́ àwọn ènìyàn burúkú, má ṣe jẹ́ kí ó sọ mí di alárìnká.+ 12  Ibẹ̀ ni àwọn aṣenilọ́ṣẹ́ ti ṣubú;+A ti tì wọ́n lulẹ̀, wọn kò sì lè dìde.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé