Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 34:1-22

Ti Dáfídì, nígbà tí ó pa orí pípé+ rẹ̀ dà níwájú Ábímélékì, tí ó fi lé e jáde, ó sì lọ. א [Áléfì] 34  Ṣe ni èmi yóò máa fi ìbùkún fún Jèhófà ní gbogbo ìgbà;+Ìgbà gbogbo ni ìyìn rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi.+ ב [Bétì]   Ọkàn mi yóò máa ṣògo nínú Jèhófà;+Àwọn ọlọ́kàn tútù yóò gbọ́, wọn yóò sì máa yọ̀.+ ג [Gímélì]   Ẹ gbé Jèhófà ga lọ́lá pẹ̀lú mi,+Ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ rẹ̀ ga.+ ד [Dálétì]   Mo wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, ó sì dá mi lóhùn,+Ó sì dá mi nídè nínú gbogbo jìnnìjìnnì mi.+ ה [Híì]   Wọ́n gbára lé e, wọ́n sì wá tàn yinrin,+Ojú wọn ni kò sì ṣeé ṣe láti kó ìtìjú bá.+ ז [Sáyínì]   Ẹni yìí tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pè, Jèhófà tìkára rẹ̀ sì gbọ́.+Ó sì gbà á là nínú gbogbo wàhálà rẹ̀.+ ח [Kétì]   Áńgẹ́lì Jèhófà dó yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká,+Ó sì ń gbà wọ́n sílẹ̀.+ ט [Tétì]   Ẹ tọ́ ọ wò, kí ẹ sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere;+Aláyọ̀ ni abarapá ọkùnrin tí ó sá di í.+ י [Yódì]   Ẹ bẹ̀rù Jèhófà, ẹ̀yin ẹni mímọ́ rẹ̀,+Nítorí kò sí àìní kankan fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.+ כ [Káfì] 10  Àwọn ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ ní díẹ̀ lọ́wọ́, ebi sì ń pa wọ́n;+Ṣùgbọ́n ní ti àwọn tí ń wá Jèhófà, wọn kì yóò ṣaláìní ohun rere èyíkéyìí.+ ל [Lámédì] 11  Ẹ wá, ẹ̀yin ọmọ, ẹ fetí sí mi;+Ìbẹ̀rù Jèhófà ni èmi yóò kọ́ yín.+ מ [Mémì] 12  Ta ni ènìyàn tí ó ní inú dídùn sí ìwàláàyè,+Tí ó nífẹ̀ẹ́ ọjọ́ púpọ̀, kí ó lè máa rí ohun rere?+ נ [Núnì] 13  Máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ahọ́n rẹ kúrò nínú ohun búburú,+Àti ètè rẹ kúrò nínú ṣíṣe ẹ̀tàn.+ ס [Sámékì] 14  Yí padà kúrò nínú ohun búburú, kí o sì máa ṣe ohun rere;+Máa wá ọ̀nà láti rí àlàáfíà, kí o sì máa lépa rẹ̀.+ ע [Áyínì] 15  Ojú Jèhófà ń bẹ lọ́dọ̀ àwọn olódodo,+Etí rẹ̀ sì ṣí sí igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́.+ פ [Péè] 16  Ojú Jèhófà lòdì sí àwọn tí ń ṣe ohun búburú,+Láti ké mímẹ́nukàn wọ́n kúrò lórí ilẹ̀ ayé pàápàá.+ צ [Sádì] 17  Wọ́n ké jáde, Jèhófà sì gbọ́,+Ó sì dá wọn nídè nínú gbogbo wàhálà wọn.+ ק [Kófì] 18  Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà;+Ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.+ ר [Réṣì] 19  Ọ̀pọ̀ ni ìyọnu àjálù olódodo,+Ṣùgbọ́n Jèhófà ń dá a nídè nínú gbogbo wọn.+ ש [Ṣínì] 20  Ó ń ṣọ́ gbogbo egungun ẹni yẹn;A kò ṣẹ́ ìkankan nínú wọn.+ ת [Tọ́ọ̀] 21  Ìyọnu àjálù ni yóò fi ikú pa ẹni burúkú alára;+Àní àwọn tí ó kórìíra olódodo ni a ó kà sí ẹlẹ́bi.+ 22  Jèhófà ń tún ọkàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ rà padà;+Kò sì sí ìkankan lára àwọn tí ń sá di í tí a ó kà sí ẹlẹ́bi.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé