Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 33:1-22

33  Ẹ fi ìdùnnú ké jáde, ẹ̀yin olódodo, nítorí Jèhófà.+ Ìyìn yẹ níhà ọ̀dọ̀ àwọn adúróṣánṣán.+   Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà lórí háàpù;+ Ẹ kọ orin atunilára sí i lórí ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín mẹ́wàá.+   Ẹ kọ orin tuntun sí i;+ Ẹ sa gbogbo ipá yín ní títa àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín, ti ẹ̀yin ti igbe ìdùnnú.+   Nítorí tí ọ̀rọ̀ Jèhófà dúró ṣánṣán,+ Gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ sì jẹ́ nínú ìṣòtítọ́.+   Òun jẹ́ olùfẹ́ òdodo àti ìdájọ́ òdodo.+ Ilẹ̀ ayé kún fún inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ti Jèhófà.+   Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Jèhófà ni a ṣe ọ̀run,+ Nípasẹ̀ ẹ̀mí ẹnu rẹ̀ sì ni a ṣe gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀.+   Ó gbá omi òkun jọ bí ẹni pé nípasẹ̀ ìsédò,+ Ó fi omi ríru sínú àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́.   Kí gbogbo ará ilẹ̀ ayé bẹ̀rù Jèhófà.+ Kí jìnnìjìnnì bá gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ eléso nítorí rẹ̀.+   Nítorí òun fúnra rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó sì wá wà;+ Òun fúnra rẹ̀ pàṣẹ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí dúró bẹ́ẹ̀.+ 10  Jèhófà fúnra rẹ̀ ti fọ́ ète àwọn orílẹ̀-èdè túútúú;+ Ó ti ké ìrònú àwọn ènìyàn nígbèrí.+ 11  Fún àkókò tí ó lọ kánrin ni ète Jèhófà yóò dúró;+ Ìrònú ọkàn-àyà rẹ̀ ń bẹ láti ìran kan tẹ̀ lé ìran mìíràn.+ 12  Aláyọ̀ ni orílẹ̀-èdè tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run rẹ̀,+ Àwọn ènìyàn tí ó yàn gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ̀.+ 13  Jèhófà wò láti ọ̀run,+ Ó rí gbogbo ọmọ ènìyàn.+ 14  Láti ibi àfìdímúlẹ̀ rẹ̀ tí ó ń gbé+ Ó tẹjú mọ́ gbogbo àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé. 15  Ó ṣẹ̀dá ọkàn-àyà wọn lápapọ̀;+ Ó ń gbé gbogbo iṣẹ́ wọn yẹ̀ wò.+ 16  Kò sí ọba kankan tí a gbà là nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ yanturu àwọn ẹgbẹ́ ológun;+ Alágbára ńlá ènìyàn ni a kò dá nídè nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ yanturu agbára.+ 17  Ẹṣin jẹ́ ẹ̀tàn fún ìgbàlà,+ Kò sì lè pèsè àsálà nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ yanturu ìmí rẹ̀.+ 18  Wò ó! Ojú Jèhófà ń bẹ lọ́dọ̀ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,+ Lọ́dọ̀ àwọn tí ń dúró de inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́,+ 19  Láti dá ọkàn wọn nídè lọ́wọ́ ikú pàápàá,+ Àti láti pa wọ́n mọ́ láàyè ní àkókò ìyàn.+ 20  Àní ọkàn wa ti ń fojú sọ́nà fún Jèhófà.+ Òun ni olùrànlọ́wọ́ wa àti apata wa.+ 21  Nítorí tí ọkàn-àyà wa ń yọ̀ nínú rẹ̀;+ Nítorí tí a gbẹ́kẹ̀ lé orúkọ mímọ́ rẹ̀.+ 22  Jèhófà, kí inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ wà lára wa,+ Àní gẹ́gẹ́ bí àwa ti ń dúró dè ọ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé