Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 32:1-11

Ti Dáfídì. Másíkílì. 32  Aláyọ̀ ni ẹni tí a dárí ìdìtẹ̀ rẹ̀ jì, tí a bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀.+   Aláyọ̀ ni ènìyàn tí Jèhófà kò ka ìṣìnà sí lọ́rùn,+ Ẹni tí ẹ̀tàn kò sì sí nínú ẹ̀mí rẹ̀.+   Nígbà tí mo dákẹ́, egungun mi ti di gbígbó nítorí ìkérora mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.+   Nítorí pé tọ̀sán-tòru ni ọwọ́ rẹ wúwo lára mi.+ Ọ̀rinrin ìgbésí ayé mi ni a ti yí padà bí ti àkókò ooru gbígbẹ ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn.+ Sélà.   Ẹ̀ṣẹ̀ mi ni mo jẹ́wọ́ fún ọ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ìṣìnà mi ni èmi kò sì bò mọ́lẹ̀.+ Mo wí pé: “Èmi yóò jẹ́wọ́ àwọn ìrélànàkọjá mi fún Jèhófà.”+ Ìwọ fúnra rẹ sì dárí ìṣìnà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.+ Sélà.   Ní tìtorí èyí, gbogbo ẹni ìdúróṣinṣin yóò máa gbàdúrà sí ọ+ Ní kìkì irúfẹ́ àkókò tí a lè rí ọ.+ Ní ti àkúnya ọ̀pọ̀ omi, wọn kì yóò kàn án lára.+   Ibi ìlùmọ́ ni ìwọ jẹ́ fún mi; ìwọ yóò fi ìṣọ́ ṣọ́ mi kúrò nínú wàhálà pàápàá.+ Ìwọ yóò fi igbe ìdùnnú yí mi ká lẹ́nu pípèsè àsálà.+ Sélà.   “Èmi yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀.+ Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.+   Ẹ má sọ ara yín di ẹṣin tàbí ìbaaka tí kò ní òye,+ Tí ó jẹ́ pé ìjánu tàbí okùn ẹran ni a fi ń ki ìtapọ́n-ún-pọ́n-ún rẹ̀ wọ̀+ Kí ó tó di pé wọn yóò sún mọ́ ọ.”+ 10  Ọ̀pọ̀ ni ìrora tí ẹni burúkú ní;+ Ṣùgbọ́n ní ti ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ni ó yí i ká.+ 11  Ẹ máa yọ̀ nínú Jèhófà, kí ẹ sì kún fún ìdùnnú, ẹ̀yin olódodo;+ Kí ẹ sì fi ìdùnnú ké jáde, gbogbo ẹ̀yin adúróṣánṣán ní ọkàn-àyà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé