Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 31:1-24

Sí olùdarí. Orin atunilára ti Dáfídì. 31  Ìwọ, Jèhófà, ni mo sá di.+ Kí ojú má tì mí láé.+ Nínú òdodo rẹ, pèsè àsálà fún mi.+   Dẹ etí sí mi.+ Dá mi nídè kánkán.+ Di ibi odi agbára tí a fi òkúta ṣe fún mi,+ Ilé àwọn ibi odi agbára láti gbà mí là.+   Nítorí ìwọ ni àpáta gàǹgà mi àti ibi odi agbára mi;+ Àti nítorí orúkọ rẹ,+ ìwọ yóò ṣamọ̀nà mi, ìwọ yóò sì darí mi.+   Ìwọ yóò yọ mí jáde nínú àwọ̀n tí wọ́n fi pa mọ́ dè mí,+ Nítorí pé ìwọ ni odi agbára mi.+   Ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé.+ Ìwọ ti tún mi rà padà,+ Jèhófà Ọlọ́run òtítọ́.+   Èmi kórìíra àwọn tí ń fiyè sí àwọn òrìṣà asán, tí kò ní láárí;+ Ṣùgbọ́n ní tèmi, Jèhófà ni mo gbẹ́kẹ̀ lé.+   Dájúdájú, èmi yóò kún fún ìdùnnú, èmi yóò sì máa yọ̀ nínú inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́,+ Ní ti pé ìwọ ti rí ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ mi níṣẹ̀ẹ́;+ Ìwọ ti mọ̀ nípa àwọn wàhálà ọkàn mi,+   Ìwọ kò sì fi mí lé ọ̀tá lọ́wọ́.+ Ìwọ ti mú kí ẹsẹ̀ mi dúró ní ibi tí ó ní àyè gbígbòòrò.+   Fi ojú rere hàn sí mi, Jèhófà, nítorí pé mo wà nínú hílàhílo.+ Ìbìnújẹ́ ti sọ ojú mi di aláìlera,+ ọkàn mi àti ikùn mi.+ 10  Nítorí pé ẹ̀dùn-ọkàn ti mú ìgbésí ayé mi wá sí òpin,+ Àti àwọn ọdún mi nínú ìmí ẹ̀dùn.+ Nítorí ìṣìnà mi, agbára mi ti kọsẹ̀,+ Àní egungun mi ti di aláìlera.+ 11  Lójú ìwòye gbogbo àwọn tí ń fi ẹ̀tanú hàn sí mi,+ mo ti di ẹni ẹ̀gàn,+ Mo sì ti dà bẹ́ẹ̀ gan-an sí àwọn aládùúgbò mi,+ Mo sì ti di ẹni tí ń fa ìbẹ̀rùbojo sí àwọn ojúlùmọ̀ mi.+ Nígbà tí wọ́n rí mi lóde, wọ́n sá fún mi.+ 12  Bí ẹni tí ó ti kú, tí kò sì sí nínú ọkàn-àyà, mo ti di ẹni ìgbàgbé;+ Mo dà bí ohun èlò tí ó bàjẹ́;+ 13  Nítorí mo ti gbọ́ ìròyìn búburú lẹ́nu ọ̀pọ̀ ènìyàn,+ Jìnnìjìnnì ń bẹ ní ìhà gbogbo.+ Nígbà tí wọ́n wọ́ jọpọ̀ ṣe ọ̀kan lòdì sí mi,+ Láti gba ọkàn mi kúrò ni wọ́n ṣe ń pète-pèrò.+ 14  Ṣùgbọ́n èmi—ìwọ Jèhófà ni mo gbẹ́kẹ̀ lé.+ Mo ti wí pé: “Ìwọ ni Ọlọ́run mi.”+ 15  Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ.+ Dá mi nídè kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá mi àti kúrò ní ọwọ́ àwọn tí ń lépa mi.+ 16  Mú kí ojú rẹ tàn sára ìránṣẹ́ rẹ.+ Gbà mí là nínú inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́.+ 17  Jèhófà, kí ojú má tì mí, nítorí pé mo ti ké pè ọ́.+ Kí ojú ti àwọn ẹni burúkú;+ Kí wọ́n dákẹ́ jẹ́ẹ́ nínú Ṣìọ́ọ̀lù.+ 18  Kí ètè èké di aláìlèsọ̀rọ̀,+ Èyí tí ń sọ̀rọ̀ láìníjàánu nínú ìrera àti ìfojú-tín-ín-rín+ lòdì sí olódodo.+ 19  Oore rẹ mà pọ̀ yanturu o,+ èyí tí o ti tò pa mọ́ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ!+ Èyí tí o ti ṣe fún àwọn tí ó sá di ọ́, Ní iwájú àwọn ọmọ ènìyàn.+ 20  Ìwọ yóò fi wọ́n pa mọ́ sí ibi ìkọ̀kọ̀ ìwọ alára+ Kúrò nínú ìpàdípọ̀ àwọn ènìyàn.+ Ìwọ yóò fi wọ́n pa mọ́ sínú àtíbàbà rẹ kúrò nínú aáwọ̀ ahọ́n.+ 21  Ìbùkún ni fún Jèhófà,+ Nítorí ó ti ṣe àgbàyanu inú-rere-onífẹ̀ẹ́+ sí mi nínú ìlú ńlá tí ó wà lábẹ́ másùnmáwo.+ 22  Ní tèmi, mo wí nígbà tí ẹ̀rù jìnnìjìnnì bò mí pé:+ “Dájúdájú, a ó pa mí run pátápátá kúrò ní iwájú rẹ.”+ Dájúdájú, ìwọ ti gbọ́ ohùn ìpàrọwà mi nígbà tí mo kígbe sí ọ fún ìrànlọ́wọ́.+ 23  Ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀.+ Jèhófà ń fi ìṣọ́ ṣọ́ àwọn olùṣòtítọ́,+ Ṣùgbọ́n ó ń san ẹ̀san lọ́nà tí ó peléke fún ẹnikẹ́ni tí ń hùwà ìrera.+ 24  Ẹ jẹ́ onígboyà, kí ọkàn-àyà yín sì jẹ́ alágbára,+ Gbogbo ẹ̀yin tí ń dúró de Jèhófà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé