Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 30:1-12

Orin atunilára. Orin ìṣílé.+ Ti Dáfídì. 30  Èmi yóò gbé ọ ga, Jèhófà, nítorí pé ìwọ ni ó fà mí sókè,+O kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi kí ó yọ̀ mí.+   Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, mo kígbe sí ọ fún ìrànlọ́wọ́, ìwọ sì tẹ̀ síwájú láti mú mi lára dá.+   Jèhófà, o ti mú ọkàn mi gòkè wá láti inú Ṣìọ́ọ̀lù pàápàá;+O ti pa mí mọ́ láàyè, kí n má bàa sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú kòtò.+   Ẹ kọ orin atunilára sí Jèhófà, ẹ̀yin ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀,+Ẹ fi ọpẹ́ fún ìrántí mímọ́ rẹ̀;+   Nítorí pé wíwà lábẹ́ ìbínú rẹ̀ jẹ́ fún ìṣẹ́jú kan,+Wíwà lábẹ́ ìfẹ́ rere rẹ̀ jẹ́ jálẹ̀ ìgbà ayé.+Ẹkún sísun lè wá gba ibùwọ̀ ní alẹ́,+ ṣùgbọ́n igbe ìdùnnú ń bẹ ní òwúrọ̀.+   Ní tèmi, mo sọ nígbà tí mo wà nínú ìdẹ̀rùn pé:+“A kì yóò mú kí n ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.”+   Jèhófà, nínú ìfẹ́ rere rẹ, ìwọ ti mú kí òkè ńlá mi dúró tokuntokun.+Ìwọ fi ojú rẹ pa mọ́; mo di ẹni tí a yọ lẹ́nu.+   Ìwọ, Jèhófà, ni mo ń pè ṣáá;+Jèhófà sì ni mo ń pàrọwà sí ṣáá fún ojú rere.+   Èrè wo ni ó wà nínú ẹ̀jẹ̀ mi nígbà tí mo bá sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú kòtò?+Ekuru yóò ha gbé ọ lárugẹ bí?+ Yóò ha sọ nípa òótọ́ rẹ bí?+ 10  Gbọ́, Jèhófà, kí o sì fi ojú rere hàn sí mi.+Jèhófà, fi ara rẹ hàn ní olùrànlọ́wọ́ mi.+ 11  Ìwọ ti sọ ọ̀fọ̀ mi di ijó fún mi;+Ìwọ ti tú aṣọ àpò ìdọ̀họ mi, o sì fi ayọ̀ yíyọ̀ dì mí lámùrè,+ 12  Kí ògo mi lè máa kọ orin atunilára sí ọ, kí ó má sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.+Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, ṣe ni èmi yóò máa gbé ọ lárugẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé