Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 3:1-8

Orin atunilára ti Dáfídì, nígbà tí ó fẹsẹ̀ fẹ ní tìtorí Ábúsálómù ọmọkùnrin rẹ̀.+ 3  Jèhófà, èé ṣe tí àwọn elénìní mi fi di púpọ̀?+ Èé ṣe tí ọ̀pọ̀ fi ń dìde sí mi?+   Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń wí nípa ọkàn mi pé: “Kò sí ìgbàlà fún un lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”+ Sélà.   Síbẹ̀, ìwọ, Jèhófà, ni apata yí mi ká,+ Ògo mi+ àti Ẹni tí ń gbé orí mi sókè.+   Èmi yóò fi ohùn mi pe Jèhófà, Òun yóò sì dá mi lóhùn láti orí òkè ńlá mímọ́ rẹ̀.+ Sélà.   Ní tèmi, ṣe ni èmi yóò dùbúlẹ̀ kí n lè sùn; Dájúdájú, èmi yóò jí, nítorí tí Jèhófà ń tì mí lẹ́yìn.+   Èmi kì yóò fòyà ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ènìyàn Tí wọ́n ti to ara wọn ní ẹsẹẹsẹ yí mi ká.+   Dìde,+ Jèhófà! Gbà mí là,+ ìwọ Ọlọ́run mi!+ Nítorí pé ṣe ni ìwọ yóò gbá gbogbo ọ̀tá mi ní páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́.+ Eyín àwọn ẹni burúkú ni ìwọ yóò ká.+   Ìgbàlà jẹ́ ti Jèhófà.+ Ìbùkún rẹ wà lára àwọn ènìyàn rẹ.+ Sélà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé