Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 29:1-11

Orin atunilára ti Dáfídì. 29  Ẹ gbé e fún Jèhófà, ẹ̀yin ọmọ àwọn alágbára, Ẹ gbé ògo àti okun fún Jèhófà.+   Ẹ gbé ògo tí ó yẹ orúkọ Jèhófà fún un.+ Ẹ tẹrí ba fún Jèhófà nínú ọ̀ṣọ́ mímọ́.+   Ohùn Jèhófà ń bẹ lórí omi;+ Ọlọ́run ògo+ ti sán ààrá.+ Jèhófà ń bẹ lórí omi púpọ̀.+   Ohùn Jèhófà lágbára;+ Ohùn Jèhófà jẹ́ ọlọ́lá ńlá.+   Ohùn Jèhófà ń fa àwọn kédárì ya; Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ń fa àwọn kédárì Lẹ́bánónì ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,+   Ó sì ń mú kí wọ́n máa tọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri bí ọmọ màlúù,+ Lẹ́bánónì àti Síríónì+ ń ṣe bí ọmọ akọ màlúù ìgbẹ́.   Ohùn Jèhófà ń fi ọwọ́ iná gé nǹkan;+   Àní ohùn Jèhófà ń mú kí aginjù jà ràpà,+ Jèhófà ń mú kí aginjù Kádéṣì+ jà ràpà.   Àní ohùn Jèhófà ń mú kí àwọn egbin jà ràpà nínú ìrora ìbímọ,+ Ó sì ń tú àwọn igbó sí borokoto.+ Nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì ń wí pé: “Ògo!”+ 10  Jèhófà ti jókòó sórí àkúnya omi;+ Jèhófà sì jókòó gẹ́gẹ́ bí ọba fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ 11  Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò fi okun fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní tòótọ́.+ Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò fi àlàáfíà bù kún àwọn ènìyàn rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé