Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 27:1-14

Ti Dáfídì. 27  Jèhófà ni ìmọ́lẹ̀ mi+ àti ìgbàlà mi.+ Ta ni èmi yóò bẹ̀rù?+ Jèhófà ni odi agbára ìgbésí ayé mi.+ Ta ni èmi yóò ní ìbẹ̀rùbojo fún?+   Nígbà tí àwọn aṣebi wá bá mi láti jẹ ẹran ara mi run,+ Níwọ̀n bí wọ́n ti jẹ́ elénìní mi àti ọ̀tá èmi alára,+ Àwọn tìkára wọn kọsẹ̀, wọ́n sì ṣubú.+   Bí àwọn adótini tilẹ̀ pàgọ́ tì mí,+ Ọkàn-àyà mi kì yóò bẹ̀rù.+ Bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi,+ Síbẹ̀síbẹ̀, èmi yóò ní ìgbẹ́kẹ̀lé.+   Ohun kan ni mo béèrè lọ́wọ́ Jèhófà+ Ìyẹn ni èmi yóò máa wá,+ Kí n lè máa gbé inú ilé Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé mi,+ Kí n lè máa rí adùn Jèhófà+ Kí n sì lè máa fi ẹ̀mí ìmọrírì wo tẹ́ńpìlì rẹ̀.+   Nítorí òun yóò fi mí pa mọ́ sí ibi kọ́lọ́fín rẹ̀ ní ọjọ́ ìyọnu àjálù;+ Òun yóò tọ́jú mi pa mọ́ sí ibi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ rẹ̀;+ Òkè lórí àpáta ni yóò gbé mi sí.+   Wàyí o, orí mi yóò yọ ju ti àwọn ọ̀tá mi tí ó yí mi ká;+ Dájúdájú, èmi yóò rú àwọn ẹbọ igbe ìdùnnú nínú àgọ́ rẹ̀;+ Èmi yóò kọrin, èmi yóò sì kọ orin atunilára sí Jèhófà.+   Gbọ́, Jèhófà, nígbà tí mo bá fi ohùn mi pè,+ Kí o sì fi ojú rere hàn sí mi, kí o sì dá mi lóhùn.+   Ọkàn-àyà mi sọ nípa rẹ pé: “Ẹ wá ọ̀nà láti rí ojú mi.”+ Ojú rẹ, Jèhófà, ni èmi yóò wá ọ̀nà láti rí.+   Má fi ojú rẹ pa mọ́ fún mi.+ Má fi ìbínú lé ìránṣẹ́ rẹ dànù.+ Kí o di ìrànwọ́ mi.+ Má ṣe ṣá mi tì, má sì fi mí sílẹ̀, ìwọ Ọlọ́run ìgbàlà mi.+ 10  Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé baba mi àti ìyá mi fi mí sílẹ̀,+ Àní Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí.+ 11  Jèhófà, fún mi ní ìtọ́ni ní ọ̀nà rẹ,+ Kí o sì ṣamọ̀nà mi ní ipa ọ̀nà ìdúróṣánṣán ní tìtorí àwọn ọ̀tá mi. 12  Má fi mí lé ọkàn àwọn elénìní mi lọ́wọ́;+ Nítorí pé àwọn ẹlẹ́rìí èké ti dìde sí mi,+ Àti ẹni tí ń gbé ìwà ipá yọ.+ 13  Ká ní èmi kò ní ìgbàgbọ́ nínú rírí oore Jèhófà ní ilẹ̀ àwọn alààyè ni+—! 14  Ní ìrètí nínú Jèhófà;+ jẹ́ onígboyà, sì jẹ́ kí ọkàn-àyà rẹ jẹ́ alágbára.+ Bẹ́ẹ̀ ni, ní ìrètí nínú Jèhófà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé