Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 26:1-12

Ti Dáfídì. 26  Ṣe ìdájọ́ mi,+ Jèhófà, nítorí pé mo ti rìn nínú ìwà títọ́ mi,+Jèhófà sì ni mo gbẹ́kẹ̀ lé, kí n má bàa gbò yèpéyèpé.+   Wádìí mi wò, Jèhófà, kí o sì dán mi wò;+Yọ́ kíndìnrín mi àti ọkàn-àyà mi mọ́.+   Nítorí pé inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ń bẹ ní iwájú mi,Mo sì ti rìn nínú òtítọ́ rẹ.+   Èmi kò bá àwọn tí kì í sọ òtítọ́ jókòó;+Àwọn tí ń fi ohun tí wọ́n jẹ́ pa mọ́ ni èmi kì í sì í bá wọlé.+   Mo kórìíra ìjọ àwọn aṣebi,+Èmi kì í sì í bá àwọn ẹni burúkú jókòó.+   Èmi yóò wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀,+Dájúdájú, èmi yóò rìn yí ká pẹpẹ rẹ, Jèhófà,+   Láti mú kí a gbọ́ ohùn ìdúpẹ́ lọ́nà tí ó dún sókè,+Àti láti polongo gbogbo iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.+   Jèhófà, mo nífẹ̀ẹ́ ibùgbé ilé rẹ+Àti ibi gbígbé ògo rẹ.+   Má ṣe mú ọkàn mi kúrò pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,+Bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe mú ìgbésí ayé mi kúrò pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ajẹ̀bi ẹ̀jẹ̀,+ 10  Àwọn tí ìwà àìníjàánu ń bẹ ní ọwọ́ wọn,+Àwọn tí ọwọ́ ọ̀tún wọ́n sì kún fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀.+ 11  Ní tèmi, èmi yóò máa rìn nínú ìwà títọ́ mi.+Tún mi rà padà,+ kí o sì fi ojú rere hàn sí mi.+ 12  Dájúdájú, ẹsẹ̀ mi yóò dúró lórí ibi títẹ́jú pẹrẹsẹ;+Inú àpéjọpọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn ni èmi yóò ti máa fi ìbùkún fún Jèhófà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé