Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 25:1-22

Ti Dáfídì. א [Áléfì] 25  Jèhófà, ọ̀dọ̀ rẹ ni mo gbé ọkàn mi gan-an sókè sí.+ ב [Bétì]   Ìwọ Ọlọ́run mi, ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé;+Kí ojú má ṣe tì mí.Kí àwọn ọ̀tá mi má yọ ayọ̀ ńláǹlà lé mi lórí.+ ג [Gímélì]   Pẹ̀lúpẹ̀lù, kò sí ẹnì kankan tí ojú yóò tì lára àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ.+Àwọn tí ń ṣe àdàkàdekè láìkẹ́sẹ járí ni ojú yóò tì.+ ד [Dálétì]   Mú mi mọ àwọn ọ̀nà rẹ, Jèhófà;+Kọ́ mi ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ.+ ה [Híì]   Mú mi rìn nínú òtítọ́ rẹ, kí o sì kọ́ mi,+Nítorí ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi.+ ו [Wọ́ọ̀]Mo ti ní ìrètí nínú rẹ láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.+ ז [Sáyínì]   Rántí àwọn àánú rẹ,+ Jèhófà, àti àwọn inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́,+Nítorí tí wọ́n wà láti àkókò tí ó lọ kánrin.+ ח [Kétì]   Má ṣe rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mi àti àwọn ìdìtẹ̀ mi.+Gẹ́gẹ́ bí inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ni kí ìwọ rántí mi,+Nítorí oore rẹ, Jèhófà.+ ט [Tétì]   Ẹni rere àti adúróṣánṣán ni Jèhófà.+Ìdí nìyẹn tí ó fi ń fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ìtọ́ni ní ọ̀nà náà.+ י [Yódì]   Òun yóò mú kí àwọn ọlọ́kàn tútù máa rìn nínú àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ̀,+Yóò sì kọ́ àwọn ọlọ́kàn tútù ní ọ̀nà rẹ̀.+ כ [Káfì] 10  Gbogbo ipa ọ̀nà Jèhófà jẹ́ inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òótọ́Fún àwọn tí ń pa májẹ̀mú+ rẹ̀ àti àwọn ìránnilétí+ rẹ̀ mọ́. ל [Lámédì] 11  Nítorí orúkọ rẹ, Jèhófà,+Àní kí o dárí ìṣìnà mi jì, nítorí tí ó pọ̀ níye.+ מ [Mémì] 12  Wàyí o, ta ni ènìyàn tí ó bẹ̀rù Jèhófà?+Òun yóò fún un ní ìtọ́ni ní ọ̀nà tí yóò yàn.+ נ [Núnì] 13  Ọkàn rẹ̀ yóò máa gbé nínú ohun rere,+Ọmọ rẹ̀ yóò sì gba ilẹ̀ ayé.+ ס [Sámékì] 14  Ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ ti àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,+Àti májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú, láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ ọ́n.+ ע [Áyínì] 15  Ojú mi ń bẹ lọ́dọ̀ Jèhófà nígbà gbogbo,+Nítorí pé òun ni ó fa ẹsẹ̀ mi yọ kúrò nínú àwọ̀n.+ פ [Péè] 16  Yí ojú rẹ sọ́dọ̀ mi, kí o sì fi ojú rere hàn sí mi;+Nítorí tí mo dá nìkan wà, a sì ń ṣẹ́ mi níṣẹ̀ẹ́.+ צ [Sádì] 17  Wàhálà ọkàn-àyà mi ti di púpọ̀;+Mú mi jáde kúrò nínú másùnmáwo tí ó bá mi.+ ר [Réṣì] 18  Wo ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ mi níṣẹ̀ẹ́ àti ìdààmú mi,+Kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.+ 19  Wo bí àwọn ọ̀tá mi ti pọ̀ tó,+Ìkórìíra lílenípá sì ni wọ́n fi kórìíra mi.+ ש [Ṣínì] 20  Ṣọ́ ọkàn mi, kí o sì dá mi nídè.+Kí ojú má ṣe tì mí, nítorí pé mo ti sá di ọ́.+ ת [Tọ́ọ̀] 21  Jẹ́ kí ìwà títọ́ àti ìdúróṣánṣán pàápàá máa fi ìṣọ́ ṣọ́ mi,+Nítorí tí mo ti ní ìrètí nínú rẹ.+ 22  Ọlọ́run, tún Ísírẹ́lì rà padà kúrò nínú gbogbo wàhálà rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé