Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 24:1-10

Ti Dáfídì. Orin atunilára. 24  Ti Jèhófà ni ilẹ̀ ayé àti ohun tí ó kún inú rẹ̀,+Ilẹ̀ eléso àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.+   Nítorí pé òun fúnra rẹ̀ ti fìdí rẹ̀ sọlẹ̀ gbọn-in gbọn-in sórí òkun,+Ó sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in sórí àwọn odò.+   Ta ní lè gun orí òkè ńlá Jèhófà,+Ta sì ni ó lè dìde ní ibi mímọ́ rẹ̀?+   Ẹni tí ó jẹ́ ọlọ́wọ́ mímọ́, tí ó sì mọ́ ní ọkàn-àyà,+Ẹni tí kò gbé ọkàn Mi lọ sínú kìkì ohun tí kò ní láárí,+Tí kò sì búra ẹ̀tàn.+   Òun yóò ru ìbùkún lọ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà+Àti òdodo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ìgbàlà rẹ̀.+   Èyí ni ìran àwọn tí ń wá a,Ti àwọn tí ń wá ojú rẹ, ìwọ [Ọlọ́run] Jékọ́bù.+ Sélà.   “Ẹ gbé orí yín sókè, ẹ̀yin ẹnubodè,+Ẹ sì gbé ara yín nà ró, ẹ̀yin ẹnu ọ̀nà wíwà pẹ́ títí,+Kí Ọba ògo lè wọlé!”+   “Ta wá ni Ọba ògo yìí?”+“Jèhófà ẹni tí ó lókun, tí ó sì ní agbára ńlá ni,+Jèhófà alágbára ńlá nínú ìjà ogun.”+   “Ẹ gbé orí yín sókè, ẹ̀yin ẹnubodè;+Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ gbé wọn sókè, ẹ̀yin ẹnu ọ̀nà wíwà pẹ́ títí,Kí Ọba ògo lè wọlé!”+  10  “Ta wá ni ẹni náà, Ọba ògo yìí?”“Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ni—òun ni Ọba ògo náà.”+ Sélà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé