Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 23:1-6

Orin atunilára ti Dáfídì. 23  Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi.+ Èmi kì yóò ṣaláìní nǹkan kan.+   Ó ń mú mi dùbúlẹ̀ ní pápá ìjẹko tí ó kún fún koríko;+ Ó ń darí mi lẹ́bàá àwọn ibi ìsinmi tí ó lómi dáadáa.+   Ó ń tu ọkàn mi lára.+ Ó ń ṣamọ̀nà mi ní àwọn òpó ọ̀nà òdodo nítorí orúkọ rẹ̀.+   Bí mo tilẹ̀ ń rìn ní àfonífojì ibú òjìji,+ Èmi kò bẹ̀rù ohun búburú kankan,+ Nítorí tí ìwọ wà pẹ̀lú mi;+ Ọ̀pá rẹ àti ọ̀pá ìdaran rẹ ni àwọn nǹkan tí ń tù mí nínú.+   Ìwọ ṣètò tábìlì síwájú mi ní iwájú àwọn tí ń fi ẹ̀tanú hàn sí mi.+ Ìwọ fi òróró pa orí mi;+ Ife mi kún dáadáa.+   Dájúdájú, ohun rere àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́ yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn ní gbogbo ọjọ́ ayé mi;+ Èmi yóò sì máa gbé inú ilé Jèhófà fún gígùn ọjọ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé