Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 21:1-13

Sí olùdarí. Orin atunilára ti Dáfídì. 21  Jèhófà, inú okun rẹ ni ọba ti ń yọ̀;+ Sì wo bí ó ti ń fẹ́ láti kún fún ìdùnnú gidigidi nínú ìgbàlà rẹ!+   Ìwọ ti fi ìfẹ́ ọkàn-àyà rẹ̀ fún un,+ Ìwọ kò sì fawọ́ ìdàníyàn ètè rẹ̀ sẹ́yìn.+ Sélà.   Nítorí pé ìwọ tẹ̀ síwájú láti fi àwọn ìbùkún ohun rere pàdé rẹ̀,+ Ìwọ sì fi adé wúrà tí a yọ́ mọ́ dé e ní orí.+   Ó béèrè ìwàláàyè lọ́wọ́ rẹ. Ìwọ fi fún un,+ Ọjọ́ gígùn fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.+   Ògo rẹ̀ tóbi nínú ìgbàlà rẹ.+ Iyì àti ọlá ńlá ni ìwọ fi sí i lára.+   Nítorí pé ìwọ sọ ọ́ di alábùkún gidigidi títí láé;+ Ìwọ fi ayọ̀ yíyọ̀ tí ó wà ní ojú rẹ mú kí ó máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀.+   Nítorí pé ọba ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà,+ Àní nínú inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ti Ẹni Gíga Jù Lọ. A kì yóò mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.+   Ọwọ́ rẹ yóò wá gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ rí;+ Ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò wá àwọn tí ó kórìíra rẹ rí.   Ìwọ yóò sọ wọ́n di ìléru oníná ní àkókò tí o yàn kalẹ̀ fún fífún wọn ní àfiyèsí.+ Jèhófà yóò gbé wọn mì nínú ìbínú rẹ̀, iná yóò sì jẹ wọ́n run.+ 10  Èso wọn ni ìwọ yóò pa run kúrò lórí ilẹ̀ ayé pàápàá,+ Àti ọmọ wọn kúrò nínú àwọn ọmọ ènìyàn.+ 11  Nítorí pé wọ́n ti dojú ohun tí ó burú kọ ọ́;+ Wọ́n ti gbìrò àwọn èrò-ọkàn tí wọn kò lè mú ṣẹ.+ 12  Nítorí tí ìwọ yóò mú kí wọ́n yí ẹ̀yìn wọn padà ní sísá+ Nípasẹ̀ okùn ọrun rẹ tí o múra de ojú wọn.+ 13  Kí a gbé ọ ga nínú okun rẹ, Jèhófà.+ Àwa yóò kọrin, a ó sì kọ orin atunilára sí agbára ńlá rẹ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé