Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 20:1-9

Sí olùdarí. Orin atunilára ti Dáfídì. 20  Kí Jèhófà dá ọ lóhùn ní ọjọ́ wàhálà.+ Kí orúkọ Ọlọ́run Jékọ́bù dáàbò bò ọ́.+   Kí ó fi ìrànlọ́wọ́ rẹ ránṣẹ́ láti ibi mímọ́,+ Kí ó sì gbé ọ ró láti Síónì pàápàá.+   Kí ó rántí gbogbo ọrẹ ẹbọ ẹ̀bùn rẹ,+ Kí ó sì gba ọrẹ ẹbọ sísun rẹ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó lọ́ràá.+ Sélà.   Kí ó fi fún ọ ní ìbámu pẹ̀lú ọkàn-àyà rẹ,+ Kí ó sì mú gbogbo ète rẹ ṣẹ.+   Àwa yóò fi ìdùnnú ké jáde nítorí ìgbàlà rẹ,+ Àti pé ní orúkọ Ọlọ́run wa ni a óò gbé àwọn ọ̀págun wa sókè.+ Kí Jèhófà mú gbogbo ìbéèrè rẹ ṣẹ.+   Nísinsìnyí ni mo wá mọ̀ pé Jèhófà ń gba ẹni àmì òróró rẹ̀ là dájúdájú.+ Ó ń dá a lóhùn láti ọ̀run mímọ́ rẹ̀+ Pẹ̀lú àwọn ìṣe agbára ńlá tí ń gbani là ti ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.+   Àwọn kan ń sọ nípa kẹ̀kẹ́ ẹṣin, àwọn mìíràn sì ń sọ nípa ẹṣin,+ Ṣùgbọ́n, ní tiwa, àwa yóò máa sọ nípa orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa.+   Àwọn wọ̀nyẹn ti wó, wọ́n sì ti ṣubú;+ Ṣùgbọ́n ní tiwa, àwa ti dìde, kí a lè mú wa padà bọ̀ sípò.+   Jèhófà, gba ọba là!+ Òun yóò dá wa lóhùn ní ọjọ́ tí a bá pè é.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé