Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 19:1-14

Sí olùdarí. Orin atunilára ti Dáfídì. 19  Àwọn ọ̀run ń polongo ògo Ọlọ́run;+Òfuurufú sì ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.+   Ọjọ́ kan tẹ̀ lé ọjọ́ mìíràn ń mú kí ọ̀rọ̀ ẹnu tú jáde,+Òru kan tẹ̀ lé òru mìíràn sì ń fi ìmọ̀ hàn.+   Wọn kò sọ ohunkóhun, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ọ̀rọ̀;A kò gbọ́ ohùn kankan láti ọ̀dọ̀ wọn.+   Okùn ìdiwọ̀n wọn ti jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀ ayé,+Àsọjáde wọn sì ti jáde lọ sí ìkángun ilẹ̀ eléso.+Inú wọn ni ó ti pa àgọ́ fún oòrùn,+   Ó sì dà bí ọkọ ìyàwó nígbà tí ó bá ń jáde bọ̀ láti inú ìyẹ̀wù ìgbà ìgbéyàwó rẹ̀;+Ó ń yọ ayọ̀ ńláǹlà gẹ́gẹ́ bí alágbára ńlá ènìyàn ti ń ṣe láti sáré ní ipa ọ̀nà.+   Láti ìkángun kan ọ̀run ni ìjáde lọ rẹ̀,Àlọyíká rẹ̀ sì dé àwọn ìkángun rẹ̀ yòókù;+Kò sì sí nǹkan kan tí ó pa mọ́ kúrò nínú ooru rẹ̀.+   Òfin+ Jèhófà pé,+ ó ń mú ọkàn padà wá.+Ìránnilétí+ Jèhófà ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé,+ ó ń sọ aláìní ìrírí di ọlọ́gbọ́n.+   Àwọn àṣẹ ìtọ́ni+ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà dúró ṣánṣán,+ wọ́n ń mú ọkàn-àyà yọ̀;+Àṣẹ+ Jèhófà mọ́,+ ó ń mú kí ojú mọ́lẹ̀.+   Ìbẹ̀rù+ Jèhófà mọ́ gaara, ó wà títí láé.Àwọn ìpinnu ìdájọ́+ Jèhófà jẹ́ òótọ́;+ òdodo ni wọ́n látòkè délẹ̀.+ 10  Wọ́n yẹ ní fífẹ́ ju wúrà, bẹ́ẹ̀ ni, ju ọ̀pọ̀ wúrà tí a yọ́ mọ́;+Wọ́n sì dùn ju oyin+ àti oyin ṣíṣàn ti inú afárá.+ 11  Pẹ̀lúpẹ̀lù, a ti kìlọ̀ fún ìránṣẹ́ rẹ nípasẹ̀ wọn;+Èrè ńlá wà nínú pípa wọ́n mọ́.+ 12  Àwọn àṣìṣe—ta ní lè fi òye mọ̀ wọ́n?+Kéde mi ní aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìkọ̀kọ̀.+ 13  Pẹ̀lúpẹ̀lù, fa ìránṣẹ́ rẹ sẹ́yìn kúrò nínú àwọn ìṣe ìkùgbù;+Má ṣe jẹ́ kí wọ́n jọba lé mi lórí.+Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, èmi yóò pé pérépéré,+Èmi yóò sì máa bá a nìṣó láti jẹ́ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ kúrò nínú ọ̀pọ̀ ìrélànàkọjá. 14  Kí àwọn àsọjáde ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn-àyà mi+Dùn mọ́ ọ, ìwọ Jèhófà Àpáta+ mi àti Olùtúnniràpadà+ mi.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé