Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 17:1-15

Àdúrà Dáfídì. 17  Gbọ́ ohun tí í ṣe òdodo, Jèhófà; fiyè sí igbe ìpàrọwà mi;+Fi etí sí àdúrà mi tí kì í ṣe ti ètè ẹ̀tàn.+   Kí ìdájọ́ mi ti iwájú rẹ jáde lọ;+Kí ojú rẹ rí ìdúróṣánṣán.+   O ti ṣàyẹ̀wò ọkàn-àyà mi, o ti ṣe àbẹ̀wò ní òru,+O ti yọ́ mi mọ́; ìwọ yóò ṣàwárí pé èmi kò pète-pèrò ibi.+Ẹnu mi kì yóò ré ìlànà kọjá.+   Ní ti ìgbòkègbodò àwọn ènìyàn,Nípa ọ̀rọ̀ ètè rẹ ni èmi fi ń ṣọ́ra fún ipa ọ̀nà ọlọ́ṣà.+   Jẹ́ kí àwọn ìṣísẹ̀ mi fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin ní àwọn òpó ọ̀nà rẹ,+Nínú èyí tí a kì yóò ti mú kí àwọn ipasẹ̀ mi kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n dájúdájú.+   Èmi ké pè ọ́, nítorí tí ìwọ, Ọlọ́run, yóò dá mi lóhùn.+Dẹ etí sí mi. Gbọ́ àsọjáde mi.+   Mú kí àwọn ìṣe inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ jẹ́ àgbàyanu,+ ìwọ Olùgbàlà àwọn tí ń wá ibi ìsádiKúrò lọ́wọ́ àwọn tí ń dìtẹ̀ sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ.+   Pa mí mọ́ bí ọmọlójú,+Fi mí pa mọ́ sábẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ,+   Nítorí àwọn ẹni burúkú tí wọ́n ti fi mí ṣe ìjẹ.Àwọn ọ̀tá ọkàn mi ń ká mi mọ́.+ 10  Wọ́n ti fi ọ̀rá ara wọn bora;+Wọ́n ti fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ ìrera;+ 11  Ní ti àwọn ìṣísẹ̀ wa, wọ́n ti yí wa ká wàyí;+Wọ́n gbé ojú wọn lé títẹ̀ kanlẹ̀.+ 12  Ìrí rẹ̀ jẹ́ ti kìnnìún tí ń yánhànhàn láti fani ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ+Àti ti ẹgbọrọ kìnnìún tí ó jókòó sí àwọn ibi tí ó lùmọ́. 13  Jèhófà, dìde; kò ó lójú;+Mú un tẹrí ba; fi idà rẹ pèsè àsálà fún ọkàn mi kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú,+ 14  Kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn, nípasẹ̀ ọwọ́ rẹ, Jèhófà,+Kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ètò+ àwọn nǹkan yìí, àwọn tí ìpín wọ́n ń bẹ nínú ìgbésí ayé yìí,+Ikùn àwọn ẹni tí o sì ti fi ìṣúra rẹ ìkọ̀kọ̀ kún,+Tí a fi àwọn ọmọkùnrin tẹ́ lọ́rùn,+Àwọn tí ó to ohun tí wọ́n ṣẹ́ kù jọ pa mọ́ fún àwọn ọmọ wọn.+ 15  Ní tèmi, inú òdodo ni èmi yóò ti rí ojú rẹ;+Dájúdájú, yóò tẹ́ mi lọ́rùn láti máa jí rí ìrísí rẹ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé