Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 16:1-11

Míkítámù ti Dáfídì. 16  Pa mi mọ́, Ọlọ́run, nítorí pé mo ti sá di ọ́.+   Mo wí fún Jèhófà pé: “Ìwọ ni Jèhófà; oore mi, kì í ṣe nítorí rẹ,+   Bí kò ṣe fún àwọn ẹni mímọ́ tí ń bẹ ní ilẹ̀ ayé.Àwọn, àní àwọn ọlọ́lá ọba, nínú àwọn ẹni tí inú dídùn mi gbogbo wà.”+   Ìrora a máa di púpọ̀ fún àwọn tí ó jẹ́ pé, nígbà tí ẹlòmíràn bá wà, wọ́n máa ń ṣe wéré tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.+Èmi kì yóò da àwọn ọrẹ ẹbọ ohun mímu wọn tí í ṣe ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀,+Èmi kì yóò sì jẹ́ kí orúkọ wọn wà ní ètè mi.+   Jèhófà ni ìpín tí ó kàn mí+ àti ti ife mi.+Ìwọ di ìpín mi mú ṣinṣin.   Àwọn ibi tí ó wuni ni okùn ìdiwọ̀n ti bọ́ sí fún mi,+Ní ti tòótọ́, ohun ìní tèmi ti já sí ìtẹ́wọ́gbà fún mi.   Èmi yóò fi ìbùkún fún Jèhófà, ẹni tí ó ti fún mi ní ìmọ̀ràn.+Ní ti tòótọ́, kíndìnrín mi ti tọ́ mi sọ́nà ní òru.+   Mo ti gbé Jèhófà sí iwájú mi nígbà gbogbo.+Nítorí pé ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mú kí n ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.+   Nítorí náà, ọkàn-àyà mi yọ̀, ògo mi sì fẹ́ láti kún fún ìdùnnú.+Pẹ̀lúpẹ̀lù, ẹran ara mi yóò máa gbé ní ààbò.+ 10  Nítorí pé ìwọ kì yóò fi ọkàn mi sílẹ̀ sínú Ṣìọ́ọ̀lù.+Ìwọ kì yóò jẹ́ kí ẹni ìdúróṣinṣin rẹ rí kòtò.+ 11  Ìwọ yóò jẹ́ kí n mọ ipa ọ̀nà ìyè.+Ayọ̀ yíyọ̀ tẹ́rùn ń bẹ ní ojú rẹ;+Adùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ títí láé.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé